Interpretation of sixteen major odu ifa (oju odu merindinlogun pt 4)posted by admin.

This write up was compiled by omo Awo Rodriguez Ifatomi an apprentice under the tutelage of babalawo Obanifa.
ODU IFA  OSA MEJI
II II
I   I
I   I
I   I
Ọsa Meji 1:

Ni… Ifa ti ẹniyan ba tun da Ifa fun ẹniyan, ti Ọsa Meji to wa nilẹ yii to jade, Ọsa Meji re bayii. Oju Ọsa Meji re bayii. Ti Ifa un ba jade si ẹniyan, Ifa sọ fun eleyii, gbogbo irin ajo rẹ ko gun. Ọran rẹ, ọna rẹ o la. Gbogbo iṣẹ rẹ o ti n bajẹ. Ko… keleyiio ṣetutu daadaa, ko si… ko rubọ fun awọn ẹgbẹrun rẹ. Ifa sọ bẹẹ, ẹgbẹrun rẹ wọn gbalẹ, wọn jẹ ki nkan ri o gun. Ifa sọ bẹẹ lodu Ọsa Meji. Ọsa Meji lo sọ bẹẹ. O ni:Isa Ọsa meji n ki arawọn jẹ jẹ jẹ, awọn lo difa fun ẹgbẹ aiye, a bu fun tọrun. Taiye n tẹ lọ, bọrọ kinni ọrun ẹ pẹhin da. Ẹgbẹ aiye n tẹlọ, bọrọọ kinni ọrun ẹ pẹhin da…Ifa ni keleyii o tete ko bọ awọn ẹgbẹrun rẹ, Ifa ni gbogbo ohun, gbogbo nkan rẹ tan o jẹ o da, yio da. Ọmọ ti o… bo ba jẹleyun lo ni wahala lori ọmọ; wọn jẹ ko, yio rọmọ bi, yio nifọkanbalẹ lori ọmọ. To ba jẹ pe iṣẹ rẹ ni, nan ba jẹ mọ lọwọ tano jẹ [ki] o rọna owo. Ifa ni gbogbo… ọna rẹ o, ọnarẹ yio la. Ko bọ awọn ẹgbẹrun nbẹ lodu Ọsa Meji. A sọ bẹẹ. Ifa ni kele…
Ọsa Meji 2:
Bo Ọsa Meji ba tun jade si eniyan, to ba gbin. Ti Ifa… Ti o ba fore nbẹ ni n jẹ to ba gbin. Ifa ni eleyii o ni isimi; wahala rẹ ti pọ ju. Bi ṣe n loke, nilodo, bi ṣe n lọ kuro ni company kan ni n bọ si company keji, ti o rowo nbẹ! Tọna rẹ o la, wọn jẹlowo, wọn o sanwo oṣu fun, ako[ko] to wa debẹ ni wọn [k]o sanwo fun un. Bo, bo, bo wa tun fi ibiṣẹ [yẹn] ilẹ, to pe jẹ koun na lọ ṣe agbẹ o, to batun doko nkan tiẹ o tun ni da. To ba tun lọ ṣagbaṣe [tenant farmer] loko, wọn o tun ni fun un lowo. Yio tun kuro loko, yio tun wale. To ba tun bẹrẹ iṣẹ mii[ran], iṣẹ rẹ o ni da. Ifa ni ko rubọ,isimi nbẹ. Ifa ni isimi yio de ba. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ. O ni:Isa n salubọ pẹrẹpẹwu a difa fun agbẹ eyi ti o ti le sa roko, eyi toko sa rele. Ẹbọ ni wọn ni [k]o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, o rubọ, riru ẹbọ ni fi ti n gbe ni, aitete ru teṣu a da ladanu, ko pẹ, ko jinna, Ifa wa ba ni laarin iṣẹgun, aarin iṣẹgun, la ba ni lẹsẹ ọbariṣa. Ta ba waiye, nṣe la ni gba. Ifa jẹ [ki] n nigba rere. Ẹlẹda mi ko gbe mi o, ki n nisimi. Ba ba waiye ṣe la nisimi.Ifa ni eleyun yio ni isimi, ko ṣetutu nbẹ. Abọru aboye, ti Ọsa Meji sọ nu un o. Loju Ọsa Meji o. Tifa wi ni .
 Translation

Ọsa Meji 1:If someone casts Ifa and Ọsa Meji comes up… This is Ọsa Meji. This is the Odu Ọsa Meji. If this sign comes up for someone, Ifa says for this person that his/her life journey is filled withobstacles, (s)he is stuck. All of his/her efforts isfor naught. This person should be careful to make a sacrifice, and should make a sacrifice for a debt to heavenly spirits. Ifa says these spirits are the ones preventing him’her from being successful. Ifa says so in Odu Ọsa Meji. Ọsa Meji says so. Ifa sys:Isa Ọsa meji n ki arawọn jẹ jẹ jẹ, awọn lo difa fun ẹgbẹ aiye, a bu fun tọrun. Taiye n tẹ lọ, bọrọ kinni ọrun ẹ pẹhin da. Ẹgbẹ aiye n tẹlọ, bọrọọ kinni ọrun ẹ pẹhin da…[Isa Ọsa meji greet each other very well, these are they who cast Ifa for the group on earth and those in heaven. We on earth are about to be disgraced, heroes of heaven don’t turn your back on us anymore. Those of us on earth are about to be disgraced, heroes of heaven don’t turn your back on us anymore.]Ifa says this person should quickly appease those spirits. Ifa says that everything that is not going well will improve. If perhaps (s)he is havetrouble because of [a lack of] children, they will ensure that (s)he will have children and have peace of mind because of it. If it is his/her workthat is troubling him/her, they will come to help him/her. Ifa says that his/her way will open up. These spirits are there in Ọsa Meji.
Ọsa Meji 2:
If Ọsa Meji comes out for someone and Ifa gives a negative message [gbin]. Gbin refers to when Ifa does not carry a positive message. Ifa says this person does not have any rest; (s)he has far too much trouble. No matter where (s)he goes, high or low, moving from one company to another, (s)he can’t make any money. His/her road will not open up. They owehim/her money. They will not pay his/her salary,as soon as (s)he arrives there, the company willnot be able to pay salaries. If (s)he decides to leave that line of work and tries to become a farmer, or goes to the river, things will still not go well for him/her. If (s)he wants to go work ona farm as a tennant farmer, they still won’t give him/her money. (S)He will leave the farm and return home. If (s)he begins a different line of work, it won’t go well. Ifa says (s)he should make a sacrifice, that (s)he will have rest. This is how Ifa said it. Ifa said:Isa n salubọ pẹrẹpẹwu a difa fun agbẹ eyi ti o ti le sa roko, eyi toko sa rele. Ẹbọ ni wọn ni [k]o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, o rubọ, riru ẹbọ ni fi ti n gbe ni, aitete ru teṣu a da ladanu, ko pẹ, ko jinna, Ifa wa ba ni laarin iṣẹgun, aarin iṣẹgun, la ba ni lẹsẹ ọbariṣa. Ta ba waiye, nṣe laa ni gba. Ifa jẹ [ki] n nigba rere. Ẹlẹda mi ko gbe mi o, ki n nisimi. Ba ba waiye ṣe la nisimi.[Isa n salubọ (child’s game) cast Ifa for the farmer who ran to the farm, and then ran back home. He offered the sacrifice that was prescribed for him. He did everything asked of him. Failure to sacrifice to Eṣu on time renders the effort a waste. Not long after that, Ifa met me in the midst of victory. We find victory at thefeet of God. When it comes to life, we are supposed to enjoy a good lifetime. Ifa let me have a good life. Ori favor me, that I may have rest. When we come to life, we should have rest.]Ifa says that person will have rest, and should make a sacrifice. That is what Ifa says in Ọsa Meji.
ODU IFA IKA MEJI
II II
 I  I
II  II
II  II
Ika Meji 1:
Eni ti a da Ifa Ika Meji fun, ta ba da Ifa Ika Meji fun, Ifa ni keleyii o ṣetutu u, Ifa lọna rẹ yio la. Ifa ni yio bọ [ni]nu ipọnju to wa. Toun na o si ri ta jẹ ṣe, ti o lọmọ, ti o laṣọ, ti o nire gbogbo. Ifa pe irọrun o de ba, ko la foriti daadaa, ko mura ṣiṣẹ, ko si maa gbadura. Gbogbo ohun ti n dun lọkan, ni Eledumare o ṣe fun patapata. Kọ lọ ṣetutu. Tori ko ni nkankan bayii, ko ra… ko bẹgbẹpe. Owo naa leniyan si fi bẹgbẹpe, nigba ti o rowo ti ẹ ṣe nkankan. Ifa ni keleyii o, ko ma… ko ma kanju… gbogbo ohun ti o ni, ni o ni i. Toun na bẹgbẹpe ti o dolowo, ti o dalọla, ti o dalaṣọ. Ifa ni bẹẹ ni. Ifa ni tori ilọsiwaju lo si dafa. Nibi Ifa gba tifa gbe jẹ bẹ. O ni:Eni Tere, Eji Tere a difa fun igbado eyi ti n loko ailere lọdun. Ẹbọ nan ni [k]o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, orubọ. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igbado wa donigba aṣọ. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igbado wa doni…Wọn ni ki igbado, wọn ni [k]o rubọ o. Ibi… Kifa ni ibi kan ni eleyii n lọ yii, o lọ moko ni, tabi oun lọ ṣiṣẹ kan nibi iṣẹ kan ni. Ifa pe ko ṣetutu [k]o to lọ ibẹ ni o ti rire tiẹ mu bọ. Ti o ti kọle, ti o ti ni aya, ti o ti nire gbogbo. Bẹẹ ni, Ifa naa sọ bẹẹ. Nan bani kigbado ko rubọ, kigbado ko ko saṣọ lara rẹ toku ni. Ihoho lo rin doko, igbado si ti rubọ [ko] to lọ. Nigba to doko bayii, to wọle, nigba tỌlọrun gbe iṣẹ rẹ de fun, gẹgẹ bi babalawo ti sọ tan ba dafa rẹ, tan ba ṣetutu ẹ. Lo ba donigba ọmọ, lo donigba aṣọ, lo donigba aya, lo donire gbogbo. Lagbo ẹ ba kun, ah! Ni n ba n yin awọn awo, lawọn awo wa n yin Ifa. Inu ẹ dun, orin awo bọ sii lẹnu un. Ẹsẹ tọna faa bayii, ijo ni n jo, ayọ ni nyọ. O ni bẹẹ, babalawo toun [wi] bẹẹ, babalawo toun sọ:Eni Tere, Eji Tere a difa fun igbado eyi ti n roko ailere lọdun. Ẹbọ nan ni [k]o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, orubọ. O gbọ riru ebọ ru o, o gbọ tete ru teṣu. O da, eru Epo, eru Ọffa, igbado wa donire gbogbo. Ki ni igbado mu bọ loko? Ihoho ni igbado rin doko, igba aṣọ lo mu bọ, igbọṣọ. Ki ni igbado mubọ loko? Igba ọmọ ni igbado mu bọ, igba ọmọ. Ki ni igbado mu bọ loko? Igba ire gbogbo, ni igbado mu bọ loko.Ifa ni eleyun… ibi ti n lọ nbẹ yio ti ṣe aṣeyori. Ko ṣetutu nbẹ loju Ika Meji. Ifa sọ bẹẹ.
Ika Meji 2:
Bifa ta tun da Ika Meji na fun eniyan loju odu, Ifani keleyun o ṣetutu ire ajinde de tan fun [almost overtaken him]. Keleyun o maa ro ara rẹ pin o, pe bo… bo wa ni toun ṣe jẹ laarin ẹgbẹ oun bayii.Ifa ni nigba ire rẹ ba de, Ifa ni oun gan, yio ma yin Eledumare ni. Nigba ire rẹ ba de, Ifa ni ire ajinde ti ṣe tan, ti o de fun eleyii o, ko fọkanbalẹ. Loju Ika Meji. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ re o. O ni:Ahun lo kakaka ahun wo gba ooṣa lo da yiwiniwini tọ ẹkun lẹhin. Alade o ji n bo ji o, a ji nde ni ti ẹkiri barapẹtu ji gidigidi.Ifa ni ire ajinde de feleyii. Ifa sọ bẹẹ. Pe ko… ko mura ṣiṣẹ, ko si ma gbadura . Ifa ni labadi nire ti o de, toun na dolọla, ti o dolọla.
Ika Meji 3:
Ifa ni keleyii o rubọ nitori ọmọ. O ti sọ bẹẹ nbẹ. Ifa ni ko rubọ nitori ọmọ. Ifa ni ko ni kan ibanu jẹlori ọmọ rara, yio si ṣe abi ọmọ. Ko si ni ri wahala nitori ọmọ, ko rubọ nbẹ. Ti o si bimọ pọ. Ifa ni eleyii yio bimọ pọ. Pe gbogbo ohun ti n dun lọkan yio bimọ ti o pọ. Ifa lọ sọ bẹẹ. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ. O ni:Okuta o ṣe mu ṣalege a difa fun Yindinyindin eyi ti n sa lọ ajuba ti n lọ re kan nile omo nibi bi. Wọn ni ko rubọ. Wọn lọmọ rẹ yio pọ. O gbọ riru ẹbọ ru o. O gbọ atete ru teṣu, o tu. Ero Epo, ero Ọffa, ẹ wa ba ni ni jẹbutu ọmọ, jẹbutu ọmọ la ba ni lẹsẹ ọbariṣa.Ifa ni… bo si bimọ pọ nu un. Ah! Wan a ni ẹ wo lagbaja, bo ṣe n bimọ bi yindinyindin. Ẹ wo lagbaja bi ṣe bi… yindinyindin. Yindinyindin bimọpọ, oju pọn [he suffered]. Kokoro naa ninu igbo lo wa. Inu igbo ni place in bush. Wọn ni ko rubọ, o si rubọ. O si bimọ pọ. Tawọn eniyan ba sọ, wọn ni ah. Wo lagbaja bo ṣe n bimọ bi yindinyindin. Look at that woman, [s]he has children like yindinyindin, so o ti ṣabiamọ [haṣe many children] daadaa. Abọru aboye, tika Meji sọ fun… ẹkọ to kọ wa nu un loju Ika Meji. Ifa ni keleyun nifọkanbalẹ. Ifa ni ire rẹ yio de o.Ika Meji 1:Anyone for whom Ika Meji is cast, Ifa says that (s)he should offer a sacrifice to open up his/herroad. Ifa says (s)he will be delivered from his/her current suffering. (S)he will see a way tomove forward, to have children, to have clothes, to have all kinds of blessings. Ifa says life will become easier and that (s)he should persevere.(S)he should be diligent in his/her work and pray. In this way, everything that is causing him/her distress will be addressed by God/Olodumare once and for all. (S)He should offer a sacrifice because (s)he is lacking something now, cannot measure up to his/her peers. It is money that helps people achieve their potential; when you have money you can accomplish a lot. Ifa says this person should not rush. Everything that (s)he does not have now, (s)he will have. (S)He will measure up to his/her peers, become wealthy, become successful, and own lots of clothes. Ifa says so.Ifa says this person came to consult Ifa because of a lack of progress. This is how Ifa came to this conclusion. Ifa said:Eni Tere, Eji Tere a difa fun agbado eyi ti n loko ailere lọdun. Ẹbọ nan ni [k]o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, orubọ. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igbado wa donigba aṣọ. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igbado wa doni…[Try once, try twice, cast Ifa for Corn who was working in the farm without profit. Corn made the sacrifice that was presecribed. Soon after that, Corn became very successful. Soon after that, Corn became very successful.]They said Corn should offer a sacrifice. Ifa said there is a place to which Corn was going, maybe he was going to the farm, or to a particular place of work. Ifa said Corn should offer a sacrifice before going to that place so that (s)he won’t miss out on his/her blessings. So he could build a house, have a wife, and receive all blessings. Yes, Ifa says so. They advised Corn to make a sacrifice. Corn did not even have enough cloth to wrap around his body. Corn went to the farm naked, but offered a sacrifice before he left. When he arrived at thefarm, God’s handiwork became manifest just asthe babalawo said when he case Ifa for Corn. Corn had countless children, owned countless amounts of cloth and all kinds of blessings. Everyone paid close attention to him Ah! He began to praise the babalawo, and the babalawoin turn praised Ifa. He was happy, and the priest’s song came to his mouth. His feet went like this; he began to dance and celebrate. He said, yes my babalawo said so, my babalawo told me:Eni Tere, Eji Tere a difa fun igbado eyi ti n roko ailere lọdun. Ẹbọ nan ni [k]o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, orubọ. O gbọ riru ebọ ru o, o gbọ tete ru teṣu. O da, eru Epo, eru Ọffa, igbado wa donire gbogbo. Ki ni igbado mu bọ loko? Ihoho ni igbado rin doko, igba aṣọ lo mu bọ, igbọṣọ. Ki ni igbado mubọ loko? Igba ọmọ ni igbado mu bọ, igba ọmọ. Ki ni igbado mu bọ loko? Igba ire gbogbo, ni igbado mu bọ loko.[Try once, try twice, cast Ifa for Corn who was working in the farm without profit. Corn made the sacrifice that was presecribed. He quickly gave Eṣu his due. People from far and near, Corn became successful. What did Corn bring back from the farm? Corn went to the farm naked, but he brought back countless clothes. What did Corn bring back from the farm? Corn brought back countless children. What did Corn bring back from the farm? Corn brought back countless blessings.]Ifa says that person… will succeed where (s)he is going. (S)He should offer a sacrifice in Ika Meji. Ifa says so.Ika Meji 2:If the Ifa sign that is cast here, Ika Meji, is cast for someone, Ifa says that person should offer asacrifice because the blessing of resurrection is almost upon him/her. This person should notlose faith in him/herself or believe him/herself to be more unfortunate than others. Ifa says when his/her blessings arrive, Ifa says that person will praise God. When his/her blessings come, Ifa says the blessing of resurrection will arrive for this person, and (s)he will have peace of mind. In Ika MejiThis is how Ifa said it. Ifa said:Ahun lo kakaka ahun wo gba ooṣa lo da yiwiniwini tọ ẹkun lẹhin. Alade o ji n bo ji o, a ji nde ni ti ẹkiri barapẹtu ji gidigidi.[Turtle squeezed himself and went into his shell, Orisa who can even pursue a tiger. ]Ifa says his/her blessings will emerge shortly. (S)He should take care in his work and pray. Ifa says his/her blessings will arrive unexpectedly, and (s)he will gain prestige and wealth.Ika Meji 3:Ifa says this person should offer a sacrifice because of trouble bearing children. Ifa says so here. Ifa says (s)he should make a sacrifice because of children. Ifa says there will be no problem of fertility, (s)he will have children. There will be no trouble because of children, so (s)he should make a sacrifice. (S)he will have many children. Ifa says (s)he will have many children, that everything that is troubling him/her… (s)he will have many children. Ifa says so. This is how Ifa said it. Ifa said:Okuta o ṣe mu ṣalege a difa fun yindinyindin eyi ti n sa lọ ajuba ti n lọ re kan nile omo nibi bi. Wọn ni ko rubọ. Wọn lọmọ rẹ yio pọ. O gbọ riru ẹbọ ru o. O gbọ atete ru teṣu, o tu. Ero Epo, ero Ọffa, ẹ wa ba ni ni jẹbutu ọmọ, jẹbutu ọmọ la ba ni lẹsẹ ọbariṣa.[A stone cannot replace eggs/larva cast Ifa for the Ant who went into the forest looking for children. They said (s)he would have many children if (s)he would prepare a sacrifice. (S)hefollowed directions and quickly gave Eṣu his due. People from far and near, come meet me inthe midst of children, we receive the gift of children at the feet of the King of the gods.]Ifa says… that is how (s)he had so many children. Ah! They said, see so-and-so, (s)he has as many children as yindinyindin [a kind of ant that travels in hoards]. See so-and-so who has as many children as yindinyindin. Yindinyindin had many children. She suffered. Itis a kind of insect inside the forest/bush. They said (s)he should make a sacrifice, so (s)he did so. People said, ah! See so-an-so who had as many children as yindinyindin. Look at that woman, she has children like yindinyindin, meaning she had many children. This is what Ika Meji says for this person. That is the lesson Ika Meji teaches. Ifa says this person will have peace of mind as his/her blessings will come
ODU IFA OTURUPON MEJI
II II
II II
 I I
II II
Oturupọn Meji 1:Ni… ta a ba da Ifa Ọlọgbọn Meji fun eniyan, Ifa niẹni kan ni n ṣe aarẹ o, ti n ṣe aisan. Kan o ṣetutu tori ẹ, ko ma ba ku. Ifa ni adiẹ ti wọn o fi ṣetutu nbẹ, adiẹ meji to tobi daadaa, toju… to ju ole wọ tan le ji gbe lọ ni ki onitoun fi ṣetutu. Nitori pe iku un, yio.. iku yio kuro lara laisan, yio bọ sara adiẹ un. Ẹn ba ti wa ji adiẹ n gbe [whoeṣer takes that hen], ni iku na o pa a. Ifa la aisan kan nbẹ nitosi eleyun, ko ṣetutu tori ẹ. Nibi Ifa gba tifa fi sọ bẹẹ ni o. O ni:Mọgbọnmọgbọn kan ko ta koko omi mọ eti aṣọ, mọramọran kan o mọ yepẹ ilẹ a difa fun Ọdunbaku ọmọ Iwarẹrẹ nifẹ. Nba ti iku desin oo,ẹyọrọ logbadiẹ irana mi lọ. Adiẹ irana ti mo gbelẹ wa da? Ẹyọrọ ti gbe lọ.Ifa ni ẹyọrọ… adiẹ na iku to fẹ pa eleyun, ara adiẹni o wa. Ba ba ti ṣe irubọ tan, a mu… awọn nkan rubọ un, la di ma apadiẹ kan, la julẹ [release it]. A ti fi nu gbogbo ara alaisan yii, a fi nu gbogbo ara rẹ, latoke dele. A wa julẹ yio ma lọ. Ẹni to ba ji adiẹ un gbe niku o pa. Ifa ni bẹẹ ni loju Ọlọgbọn Meji.Ọlọgbọn Meji 2:Lodu Ọlọgbọn Meji naa si ẹ wẹ, tifa ti ni keleyii oṣọra fọrẹ, pe ọrẹ rẹ kan nbẹ amọran ti o ma ba da. Bi o ṣe ṣe iku pa ni o, ko ma gbọ o. Ti o ba ma iru ti ṣe ninu awọn ọrẹ rẹ, ọrẹ naa ẹhin rẹ kako bayii, ti o maa n yan, ti o maa n yan bayii. Ninu awọn ọrẹ rẹ un. Ko ṣọra fun un. Nibi Ifa gba tifa fi jẹ bẹ. O ni:Ọgbọn lẹni mọ ẹni o mọ eru, ẹni ba meru ẹni o mọ ẹtan awọn lo difa fun Alabahun Ọgangan eyiti o fi eso mu Ikoko bọ apa baba rẹ ninu oko.Alabahun Ọgangan re ati Ikoko ọrẹ ni wọn. BabaAlabahun o si ni Ooṣa [Oriṣa] kan ti n maa bọ ninu oko rẹ, ko to ku, igi Apa ni. Ibẹ naa looṣa naa wa. Nigba baba Alabahun wa ku, Alabahun wa ri ohun ti n fi bọ lọdun yii. Lo wa lọ ba ọrẹ rẹ. O ni, “Iwọ ọrẹ mi,” o ni, “iwọ nu o. Oun mọ pe o fẹran ẹran jijẹ. Gbogbo ẹbi ti n pa o yii, to ba ti de nu oko baba oun nisiyin o rẹran jẹ daadaa.” Ikoko lo yaa, nigba ti ẹbi si n pa a, nan ba lọ, igba ti wọn dohun, Ikoko ni “ọrẹ mi ẹran oun da?” O ni, “ah, o lo gun igi yii lọ ni, to ba ti gun igiyii, o lo ri wọn bi wọn ṣe pọ lọ lọọkan. Alabahun si ti dọgbọn kẹ okun silẹ. To ti pokun so… Lo ti pokun si pe ko le so. Lo ni, “Iwọ ọrẹ ko gun igi, lori ki… ko gun igi lọ. Kọkọrun bọ bi okun un.” O ni o ri bẹran ṣe pọ to. Bọrẹ rẹ si gungi, lo ba kọrun bọ ibi okun un, bo ṣe yẹgi fun nu un. Bokun ṣe fun Ikoko lọrun nu un. Nigba [ti] o ku bi ẹmi kan si lọrun, lo ba ge okun yẹn, ‘gban’ lọrẹ jan mọlẹ, lo ba du [slaughter] u, lo fọbẹ du si lọrun. Sigi pe… “Iwọ igi yi o, oun bọ o. Baba oun o.” La sa ṣetutu, o sa bọ bi wọn ṣe maa n bọ ọ. Lo ba tan ọrẹ rẹ pa. Ifa ni keleyii o ṣọra fun ọrẹ, kan ma ba tan pa a. Loju Ọlọgbọn Meji. Bifa na ṣe sọ nu un o. Abọru aboye o.Oturupọn Meji 1:If Ọlọgbọn Meji is cast for someone, Ifa says there is someone who is sick or has an illness. The people around the aflicted person should make a sacrifice because so that the sick person does not die. Ifa says that hens should be used in the sacrifice. Specifically two fat hens that would tempt theives to steal them. Death with leave the body of the sick and go into the body of the hen. Whoever steals the chicken, death will kill him/her. Ifa says the sickperson is close to this person, so (s)he should offer a sacrifice because of it. This is how Ifa said it, Ifa said:Mọgbọnmọgbọn kan ko ta koko omi mọ eti aṣọ, mọramọran kan o mọ yepẹ ilẹ a difa fun Ọdunbaku ọmọ Iwarẹrẹ nifẹ. Nba ti iku desin oo,ẹyọrọ logbadiẹ irana mi lọ. Adiẹ irana ti mo gbelẹ wa da? Ẹyọrọ ti gbe lọ.[A wise person cannot tie water to the end of his clothes, a seer cannot know the number of grains of sand on the ground cast Ifa for Ọdunbaku the child of Iwarẹrẹ in Ifẹ. I would have been dead since last year, but the fox took my sacrificial hen away. Where is my sacrifical hen? The fox has taken it.]Ifa says that death who wanted to kill this person, but will move to the body of the chicken. Once the sacrifice has been finished, the chicken should be released. They should rub the chicken against the body of the sick person from head to toe. Then the the chicken should be released, and it will go. Whoever steals the chicken will be taken by death. Ifa says so in Ọlọgbọn Meji.Ọlọgbọn Meji 2:In Ọlọgbọn Meji also, Ifa says that this person should beware of friends. That one particular friend will give advice that is not good, the kind of advice that will lead to death. (S)He should not listen to that friend. If (s)he doesn’t know who it is amongst his/her friends, the friend’s back will be hunched over like this. (S)He will also sway like this while walking. The person is amongst his/her friends and (s)he should beware of that friend. This is how Ifa came to this conclusion. Ifa said:Ọgbọn lẹni mọ, ẹni o mọ eru, ẹni ba meru, ẹni o mọ ẹtan awọn lo difa fun Alabahun Ọgangan eyiti o fi ẹsọ mu ikoko bọ apa baba rẹ ninu oko.[One only knows wisdom, one does not know tricks, one who knows tricks does not know deceit cast Ifa for Alabahun Ọgangan (Turtle) the one who used guile to offer Hyena as a sacrifice to the Apa tree of his father in the farm.]Alabahun Ọgangan (Turtle) and Hyena were friends. Turtle’s father had an Oriṣa that he worshipped in his farm. It was an Apa tree. Thatis were the Oriṣa was. When Turtle’s father died,Turtle began looking for what he could use to worship the Apa tree that year. He went to meet his friend Hyena. He said, “Hey my friend! I know how much you like to eat meat. I’m sure you’re hungry now, but if you come with me to my father’s farm, you will see so many animals to eat.” Hyena gladly accepted the offer, and since he was hungry, they left. When they got there, Hyena said, “My friend, where are all these animals?” Turtle said, “Ah, go climb that tree. When you reach the top, you will see just how many animals there are.” Turtle had alreadymade a kind of noose and tied it to the tree so he could hang Hyena with it. He said, “My friend,climb up the tree. Get up there nad put your head through that loop and you will see so many animals to eat.” So his friend climbed the tree, he put his head through the noose, and Turtle pulled on the rope. That is how Turtle used the rope to strangle Hyena. When Hyena had almost drawn his last breath, Turtle cut the rope. GBAN, his friend fell to the ground. Then Turtle used a knife to cut Hyena’s throught and slaughter him. Then he said to the tree, “O tree! Iam worshipping you! Father, I am honoring you!” and did everything required of him for the ritual. He tricked and killed his friend.Ifa says this person should watch out for a friend who will try to trick and kill him/her in Ọlọgbọn Meji. That is how Ifa said it.
ODU IFA OTURA MEJI
 I  I
II  II
 I  I
 I  I
Otura Meji 1:Odu Ifa ti a dalẹ yii, Otua Meji lo wa nlẹ yii. Ẹni tada a fun, Ifa sọ fun eleyii wipe ko mojuto ẹsin. To ba jẹ pe musulumi ni, ko lọ kewu. Ko mojuto ẹsin daadaa, kọ lọ kewu o, to ba jẹ pe iran musulumi ni. To ba jẹ pe eleyii, yio ṣe babalawo, to si tun jẹ pe iran musulumi ni baba rẹ tẹlẹ, ko ṣe mejeji pọ, o bara wọn mu. Ifa laṣeyọri wa fun eleyii. Kewu gidi ni kọ lọ ke, kewu lọna rẹ. Loju Otua Meji. Ifa ni to ba ti lọ kewu, gbogbo nkan o wa rọ ọ lọrun. Aṣeyọri yio de ba. Ifa sọọ bẹẹ loju Otua Meji. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ. O ni:Dagadamba n fura ọsẹyẹ oko gbọ mọle Aworokonjobi a dia fun Ọrunmila. Baba n lọ re gba gambi, a gba gambi o, a gba a wa, a le we lawani a gbe ede bọrun. Ifa wa wa di mọle.Ifa ni keleyii lọ kewu, Ifa… to ba ti kewu, o laṣeyọri wa fun. Gbogbo ohun pe, oke ṣoro rẹ, o ni yio lọle ni. Bẹẹ ni Ifa sọ, lodu Otua Meji. Bẹẹ ni.Otura Meji 2:Otura Meji… Ifa yii tun sọ feleyii wipe keleyii kọ ṣọra rẹ daadaa. Ko mọ pe agba nbẹ. Ẹni to ba banibi kan, to ba jọga fun, ko gba lọga. Kaṣeyọri o le ba de ba. Tori ohun toun na ba ṣe ni o gba o. Ifa ni teleyii ba ṣe ni o gba, ko ma huwa buruku fun ẹni to jẹ aṣaju rẹ. Ko ma rifin, Ifa ni to ba ṣe fun agba n loun na o gba. Ifa ni to ba ti le tẹriba fagba, to si gba pe ẹni to wa iwaju yii, ọga lo jẹ fun oun, Ifa ni yio ṣaseyọri. Loju Otua Meji naa losọ bẹẹ. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ fun eleyii ni pe. O ni:Araba ni baba, ara ba ni baba ẹni ti a ba la ba ni baba. Ẹni ti a ba ninu ahere ni baba a difa fun Baba Imọle abiewu gẹrẹjẹ eyi ti o fi gbogbo aiye ṣe ọfẹ jẹ. Ta ni baba eriwo. Araba ni baba eriwo. Araba…Ifa ni keleyii o gba agba to ba ti jẹ aṣaju rẹ, ko ma gba pe baba ni. Ifa ni nigba naa ni o laseyọri.Ifa sọ fun eleyun baun. Bẹẹ ni ta ba… n tifa ba sọ fun. Ko huwa daadaa, ko ma ṣe daadaa. Ifa la… o laseyọri, o lo wa fun un.Otura Meji 3:Ifa leleyii si wẹ, yio lọ mọ iwọn ara rẹ. Ẹni ta ba da da Ifa yii fun. Ko lọ mọwọn ara rẹ. Kọ ma ṣe ṣe arimi. Nitori pe n tifa fi n ki lọ fun eleyii pe keleyii o lọ mu ara, ko ma ṣe ṣe arimi pe aarin ọta lo wa. Aarin ọta lo wa o. To ba si ni suuru daadaa, to kun fadura, Ifa ni yio ṣẹgun awọn ọta un, ti o wa di ọba le gbogbo wọn lori patapata. Tio dọba le wọn lori. Loju Otura Meji. Bẹẹ ni ibi tifagba to fi sọ bẹẹ nii…. Fun eleyii. O ni:Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi tio mu jọba igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba.Erinmọdo re, hmm, oun na mu jọba igi loko. Wọn ni kerinmọdo o rubọ nigba igba iwasẹ. Nitori pe, aarin ọta lo wa. Gbogbo ẹgbẹ rẹ patapata, wọn bori ẹ ni. Wọn ba ṣọta pe, ṣoun ni kan ni. Ṣoun ni kan lo rẹwa ni. Wọn ṣa n ditẹ mọ ọ. O wa meji kẹta, [o daarun] o gboko awo lọ. Oun na kuro ninu iyanjẹ ibi. O loun yio ṣẹgun ọta. O meji, kẹta, o daarun, o gboko awo lọ. O fowo Ifalẹ, a dafa fun un. Awọn babalawo sọ funun pe oun le ṣẹgun ọta, ninu ohun to bọ si naa ni. Naa lo da…Ni eleyii dafa si. O ni bẹẹ ni, ni ko rubọ. Wọn ni to ba ti rubọ, wọn ni gbogbo ohun tan a fi iya jẹun, tan ba ṣọta oun, ni o wa dọba le [wọn] lori i. Bọ Ọrunmila ṣe ṣefa fun Erinmọdo nu un. Bo ṣe dọba le gbogbo wọn lori nu un. Tẹ ba kirinmọdo ni ninu igbo doni doni, o rẹwa, rabata bayii lori, kosi ohunn ti wọn o fi ṣe. Bẹẹni,ni n ba n jo ni n ba n yọ. Ngbo o ṣẹgun ọta tan. Oni bẹẹ babalawo toun [wi] bẹẹ, babalawo toun sọ:Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi tio kẹhin igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba. Ọrunmila lo gberimọdo niyawo. Ifa waa ferinmọdo jọba.On ṣe Ifa wa ferinmọdo jọba ooo.Ifa wa ferinmọdọ jọba.Ọrunmila lo gberinmọdo niyawo.Ifa wa ferinmọdo jọba.Bo ṣe jẹ ọba le gbogbo awọn igi ẹgbẹ rẹ lori nu. Ifa ni eleyii yio dọba le gbogbo awọn ota lori, ko… ko rubọ nbẹ. Bẹẹ ni, Ifa lo sọ bẹẹ. Loju Otura Meji naa ni.Otura Meji 4:Ifa tun sọ fun eleyii naa, huh, ko mọ iwọn ara rẹ, aarin ọta lo wa. Tori ojọjumọ nan… fi ṣepe, gbogbo ohun ti n ṣe o tẹ wọn lọrun. Ṣugbọn gbogbo epe ti wọn ṣe yii, to ba ti le rubọ, tawọn babalawo jawe Ifa fun un, Ifa lepe naa yio yi pada ti o mu ni lari ni. Ti o lowo lọwọ, ti o la, ju gbogbo ti wọn ba ṣe ọta lọ. Ifa lo sọ bẹẹ. Nibi Ifagba to fi sọ bẹẹ ni o. O ni:Ka mu irin pọnna ka fi ya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lọrun, baba wọn ku o, won o jogun ẹru. Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ. Bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe,Wọn ni ki baba Ọrunmila o rubọ, nigba awọn babalawo da a, wọn ni [ko] rubọ. Gbogbo wọn tan ṣepe fun baba yii. Pe ayipada rẹ owo ni babao fi ni o. Bi baba ṣe ṣetutu nu o. Baba gbọ riru o ru o, baba gbọ titu o tu. O gbọ oharaka ẹbọ loju ọpọn, o ha. Aṣẹhin wa, aṣẹhin bọ, Ifa wa ba babani jẹbutu ire. Baba n jo, baba n yọ. O ni bẹẹ nan babalawo toun wi, o ni:Ka mu irin pọnna ka fi ya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lẹka lọrun, baba wọn ku o, won o jogun ẹru.Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ, bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe, n jẹ bi ẹ ba gbe mi ṣepe ngba yii bi n ṣai ni owo lọwọ. Egbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo fi faya laya. Ẹgbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo fi n bimọ lemọ. Egbo egbo, ẹwa ẹwa, bẹ tun ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo wa nire gbogbo. Egbo egbo...Ifa ni keleyii o lọ rubọ, Ifa nire gbogbo ni o… ni o ni nbẹ. Gbogbo ọta tan ba ṣe ayipada yio de ti o dolowo. Bẹẹ ni Ifa sọ loju… loju Otua Meji. Abọruaboye, nifa. Ifa sọ bẹẹ.Otura Meji 1:The Ifa sign that is cast here, Otura Meji is the sign here. Anyone for whom it is cast, Ifa says this person should focus on his/her religion. If (s)he is a Muslim, (s)he should go to Qur’anic school. (S)he should focus intensely on his/her religion, go to Qur’anic school, if (s)he is a Muslim. If he is a babalawo, and comes from a line of Muslims, he should study and practice the two religions together. Ifa says success is there for this person. (S)He should be diligent inIslamic studies because this is his/her path in life. This is what Otura Meji says. Ifa says if (s)he studies Islam, everything will be easy for him/her. Success will come to this person. Ifa says so in Otura Meji. This is how Ifa said it, Ifa said:Dagadamba n fura ọsẹyẹ oko gbọ mọle Aworokonjobi a dia fun Ọrunmila. Baba n lọ re gba gambi, a gba gambi o, a gba a wa, a le we lawani a gbe ede bọrun. Ifa wa wa di mọle.[Dagadamba n fura it makes a bird in the bush to understand Islam, Aworokonjobi cast Ifa for Ọrunmila. Baba went to collect Gambi. We received Gambi o, we brought it back. We can don the turban, and we can speak their langauge. Our Ifa became Muslim.]Ifa says this person should go to Qur’anic school. If (s)he does so, (s)he will find success there. The way will be made easy for him/her. This is what Ifa says in Otura Meji.Otura Meji 2:Ifa also says for this person that (s)he should be very careful. (S)He should recognize that there are powerful people out there. (S)He should accept the person who (s)he meets as his/her boss or master so that (s)he may find success. This is because (s)he will be treated inthe same way (s)he acts. Ifa says when (s)he accepts that person, that (s)he should not behave poorly toward his/her leader. (S)He should not be disrespectful, and that (s)he will receive the same treatment that (s)he gives his/her leader. Ifa says that if (s)he has respect for his/her elder and accepts the person who is above him/her, the boss/master, Ifa says (s)he will succeed. Otura Meji says so. This is how Ifasaid it for this person. Ifa said:Araba ni baba, ara ba ni baba ẹni ti a ba la ba ni baba. Ẹni ti a ba ninu ahere ni baba a difa fun Baba Imọle abiewu gẹrẹjẹ eyi ti o fi gbogbo aiye ṣe ọfẹ jẹ. Ta ni baba eriwo. Araba ni baba eriwo. Araba…[The high priest of Ifa is the leader, the person related to you is your father. The person who precedes you is your leader; the person you meet in the hut is your leader cast Ifa for Baba Imọle (the Prophet Muhammed) with a long flowing gown the one who claimed the whole world as his own. Who is the leader of the scholars? The Araba is their leader.]Ifa says that this person should accept his/her seniors or superiors and respect their authority. Ifa says that is how (s)he will succeed. Ifa says so for that person. Yes, this is what Ifa said, that(s)he should behave well, and do well by his/hermaster. Ifa says success is there for him/her.Otura Meji 3:Ifa also says for this person that this particular one must know his/her limits. (S)He shouldn’t show off or try to be something (s)he is not, because Ifa warns this person to be careful andnot to show off since (s)he is in the midst of enemies. If (s)he is very patient, and is diligent in prayer, Ifa says (s)he will defeat his/her enemies, and (s)he will become the ruler over every last one of them. (S)He will rule over themin Otura Meji. Yes, this is how Ifa said it for this person. Ifa said:Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi tio mu jọba igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba.[A raod leads from here, a road leads from there. When two roads merge, they taper down, cast Ifa for the Erinmọdo tree who who was made king over the trees in the forest. Ifa declared Erinmọdo king.]Ẹrinmọdo, hmm, he is the one they made king ofthe trees in the forest. Erinmọdo was instructed to offer a sacrifice in the time of the ancestors because she was surrounded by enemies. Everylast one of her mates was more successful than she was. They antagonized her, saying, “Is she the only one? Is she the only one who is beautiful?” So they plotted against her. Erinmọdo put two and two together and realizedthat she needed the advice of Ifa. She said she must find a way out of this trouble and defeat her enemies. She decided that she must seek the help of Ifa priests and went to consult Ifa. The babalawo told her that she would defeat her enemies in the matter at hand. They said she should offer a sacrifice, so that all the suffering that her enemies were trying to inflict on her, everyone who had become her enemy, she would rule over them. That is what Ọrunmila did for Erinmọdo and she came to ruleover all of the other trees. Up until today, if you see Erinmọdo, it is beautiful and enourmous likethis, and there is nothing anyone can do about it. She danced and rejoiced when she defeated her enemies. She said, my babalawo told me so,my babalawo said:Ọna kan ti n ihin wa, ọna kan ti ohun wa. Ipade ọna meji a bi ẹnu ṣonṣo a dia fun Erinmọdo eyi tio kẹhin igi loko. Ifa lo wa ferinmọdo jọba. Ọrunmila lo gberimọdo niyawo. Ifa waa ferinmọdo jọba.[A raod leads from here, a road leads from there. When two roads merge, they taper down, cast Ifa for the Erinmọdo tree who who was made king over the trees in the forest. Ifa declared Erinmọdo king.]On ṣe Ifa wa ferinmọdo jọba ooo.Ifa wa ferinmọdọ jọba.Ọrunmila lo gberinmọdo niyawo.Ifa wa ferinmọdo jọba.[She sang: Ifa made Erinmọdo the king ooo.Ifa made Erinmọdo the king.Ọrunmila took Erinmọdo as his wife.Ifa made Erinmọdo the king.]Otura Meji 4:Ifa also says for this person, huh, that (s)he should know his/her place, because (s)he is in the midst of enemies. Everyday people are trying to curse him/her, and everything that (s)he is doing does not please them. However, all of the curses they try to place on him/her, if (s)he offers a sacrifice and the babalawo prepare medicine for him/her, Ifa says the curses will be turned into blessings. (S)he will become rich, richer than all of his/her enemies. Ifa says so. This is how Ifa said it, Ifa said:Ka mu irin pọnna ka fiya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lọrun baba wọn ku o, won o jogun ẹru. Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ, bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe,[Let us take iron to make the tribal marks, let us mark the face of the child, let use a hot leave (like stinging nettle) to mark the neck of the child, their father died, they did not inherit any slaves. When the mother died, they did not inherit her beads. They did not even inherit the clothes of their father is the one who cast Ifa forỌrunmila when they were cursing him everyday.]The babalawo told Ọrunmila to offer a sacrifice when they cast this Ifa sign. All of his enemies were trying to curse him. Baba turned the curse into money. Baba quickly made a sacrifice. He did everything asked of him and followed directions exactly. Not long after that, Ifa met him in the midst of blessings. Baba was dancing and rejoicing. He said his babalawo had told him it would be so. He said:Ka mu irin pọnna ka fi ya ọmọ loju, ka fi esi ya ọmọ lọrun, baba wọn ku o, won o jogun ẹru. Iya wọn ku o, wọn o jogun ilẹkẹ, bẹẹni won o jogun akisa jinni a difa fun Ọrunmila. Wọn fi jojumọ wọn fi baba ṣepe, n jẹ bi ẹ ba gbe mi ṣepe ngba yii bi n ṣai ni owo lọwọ. Egbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mo fi faya laya. Ẹgbo ẹgbo, ẹwa ẹwa, bẹ ṣe n gbe mi ṣepe nigba yii mofi n bimọ lemọ. Egbo egbo, ẹwa ẹwa, bẹ tun ṣe ngbe mi ṣepe nigba yii mo wa nire gbogbo. Egbo egbo...[Let us take iron to make the tribal marks, let us mark the face of the child, let use a hot leave (like stinging nettle) to mark the neck of the child, their father died, they did not inherit any slaves. When the mother died, they did not inherit her beads. They did not even inherit the clothes of their father is the one who cast Ifa forỌrunmila when they were cursing him everyday.I may not have money when you try to curse me. When you try to curse me, I will use it to have many wives. When you try to curse me, I will use it to have many children. When you try to curse me, I will use it to get all kinds of blessings…]Ifa says that this person should offer a sacrificeand (s)he will receive all kinds of blessings. Everything his/her enemies are doing will turn into a blessing of money. Ifa says so in Otua Meji.
ODU IFA IRETE MEJI
 I I
 I  I
 II II
  I   I

Irẹtẹ Meji 1:Irẹtẹ Meji lo jade si eleyii. Ifa ni, keleyii o rubọ o, ko si mura ṣiṣẹ. Ifa wipe aṣeyọri si wa fun un. Koma ṣọlẹ, ko mura ṣiṣẹ, ko mojuto, ki wọn da iṣẹ tin ṣe mọ. Kookọ rẹ o ma bajẹ, tori pe eni ti wọn o ba mọ iṣẹ ti n ṣe, ookọ rẹ yio bajẹ. Ifa sọ bẹẹ. Ifa ni iṣẹ teleyii ba yan laayo, ko jẹ kaiye mọọ mọ oun. Kookọ rẹ o ma ba bajẹ, dọjọ alẹ. Ṣugbọn ti aiye ba ti mọọ mọ, bọya mekaniki ni o, ki wọn mọ pe mekaniki ni. Bọya babalawo ni o, ki wọn mọ pe babalawo ni o. Bọya driver ni o, ko jẹ ki wọn mọ pe driver ni. Ifa ni… nigba naa ni yio yẹ eleyii kalẹ, ṣugbọn tan o ba mọ iṣẹ ti n ṣe, eh! Iṣẹkinni lamarin… Ifa ni keleyii o ma ba orukọ ara rẹjẹ, ko ma ba ti baba rẹ jẹ. Iṣẹ to ba fẹ ṣẹ, ko yan laayo. Kire rẹ o le dọjọ alẹ, ko le ni yii dọjọ alẹ. Ifa na lo sọ bẹẹ, loju Eji Ẹlẹmẹrẹ; Irẹtẹ Meji ni n jẹ bẹ. Bẹẹ ni tifa gba tifa fi jẹ bẹẹ. O ni:Ẹẹrun n yan foto kete a difa fun Atọka eyi ti ṣe Ilari Eledumare. Ilari o ba roko, emi iba ṣe Ilari Ifa. Emi iba ma yọ ṣẹṣẹṣẹ. Ero Ẹpo, ero Ọffa, Ilari o ba roko emi iba ṣe Ilari Ifa. Ta ni o mọ pe Ilari Ifa lemi ṣe?Nisiyin, emi jẹ babalawo nisiyin. Gbogbo eniyan nan mọ pe babalawo ni mi. So, ah, lagbaja, babalawo mo ni. Ni Awiṣe Ifarinwale Araba Modakẹkẹ, babalawo mo ni. Ah, ni akẹkọ mọ ni Deji lati Amẹrika. Eh, prọọfu, ni Professor Ajibade ah, professor mọ ni ni kampọsi. Gbogboeniyan mọ iṣẹ to yan laayo. To ba ti, Ifa ni… keleyii ko jẹ ka yio mọ iṣẹ rẹ mọọ kookọ rẹ o ma ba jẹ. Ifa sọ bẹẹ… fun eleyii, pe ko mojuto iṣẹ rẹ. Bẹẹ ni, loju Eji Ẹlẹmẹrẹ.Irẹtẹ Meji 2:Ifa yii na tun sọ fun eleyii wipe, ko rubọ, ko ṣetutu laarin ọmọ iya mẹta. Ko ma jẹ pe nigbaa tenikan ba daa, ti enikeji o ni daa. Ko ṣetutu nbẹ, ki gbogbo wọn le ba jọ ni lari papọ. Loju Eji Ẹlẹmẹrẹ. Ifa lọ sọ bẹẹ. Nigba ti aburo to lowo, tẹgbọn o lowo. Ti nkan lo k… Ifa ni ko ṣetutu ki gbogbo wọn jọ le lowo papọ. Igba naa ni o to dun. Bẹẹ ni, nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ. O ni:Ajalu yeke awo omi ni ṣawo omi. Ajalu pẹtẹ awoẹẹrẹ ni ṣawo ẹẹrẹ. Ajalu sorosan lo difa fun kankan eni ti n re aiye ainiku. Won ni ki awon mẹtẹẹta o rubọ. Ọmọ iya kan naa ni wọn. Omi, ọ gbọ riru, o ru o; o gbọ titu, o tu. Ko pẹ, ko jinna, Ifa wa ba larin iṣẹgun. Kankan gbọ riru, o ru o; o gbọ titu, o tu. Ko pẹ, ko jinna, Ifa wa ba larin iṣẹgun. Ẹẹrẹ nikan ni n bẹ lẹhin ti o rubọ.Nna ni o jẹ tiẹ o gun di oni. Ti omi ba ṣan lọ bayii, ti eniyan ba de oju odo, omi o maa ṣan lọ. Aa loun ṣẹbọ fun wọn teretetete. Oun ṣẹbọ fun wọn… tereteterete. Omi mọ ni. Bẹ ba de inu odo nisiyin, tẹ daru gburugburubu bayii, igba ti yio bafi pe iṣẹju kan si meji, o tun ti toro pada. Ẹbọ rẹ to ru lọjọ na lo jẹ ki… ki ile aiye rẹ o ma mọ. Kọinkọin, tẹniyan fi ma wẹ, iba jẹ nan ti n… tẹ ba ti wẹ, tẹ yan bayii, ṣe lomi o… aa lo ṣẹbọ fun oun mọ ṣekeṣekeṣeke, naa ni kankan, kankan wi. Ẹẹrẹ… ẹẹrẹ a ni airubọ toun lọ jẹ koun mọ ṣe pẹtẹ pẹtẹ. Bẹ ba tẹsẹ bọ bayii, yio mọ yin lẹsẹ madimadi. Ibẹ n tiẹ ra si, Ifa ni keleyii rubọ ko ma jẹ, ko ma jẹ pe ti o ra laarin ẹgbẹ rẹ, ki tiẹ o le ba daa. Ifa sọ bẹẹ loju Eji Ẹlẹmẹrẹ.Irẹtẹ Meji 3:Ifa naa n tun sọ fun eleyii ko le bọnu iṣẹ, ko le bọnu iya, kọ lọ tẹfa, kọran rẹ o le loju. Ifa lọran eleyii ko loju. Ko rojutu ile aiye rẹ, ko rọna abayọ.O ṣiṣẹ ko lojutu, o si ṣowoṣowo [ṣe ni n jere ti] ṣe ni n ṣọti n bẹ, ko jere. Ifa ni keleyii lọ tẹfa, aarin ọta lo wa, kan o le ba jẹ o lowo. Ki ayipada rie o le ba de ba. Ifa lọ sọ bẹẹ. Ifa na lọ sọ bẹẹ. O ni:Poro bayii, ala bayii a difa fun Irẹ ti o tẹ meji ti o si la gudugudu. Wọn ni ki Irẹ, wọn ni o lọ, ko lọ tẹfa, ko le ba la, ko le ba ni lari. Ki wahala rẹ o le ba dopin. Irẹ ma gbọ, o mọ ru, o lọ tẹfa. Lọrọ rẹ ba gun, lo ba ko [click]. Ni gbogbo ayipada ba desi iṣẹ aje rẹ. Bo ṣe la nu. To lowo, hmm. Ni n ba yin awọn awo, lawọn awo wa n yin Ifa. Ijo ni n jo,ayọ ni n yọ, ẹsẹ tọ na fa bayii. Ni ijo bọ si lẹsẹ, torin awo ko si lẹnu. O ni bẹẹ babalawo toun [wi]bẹẹ, babalawo toun sọ. Poro bayii ala bayi a difafun Irẹ ti o tẹ meji ti o si la gudugudu. Asẹhin waasẹhin bọ, igba Irẹ tẹ meji lo wa la gudugudu. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igba Irẹ tẹ meji lo wa dalaya. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igba Irẹ tẹ meji lo wa da alabiamọ. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igba Irẹ wa tẹ meji lo wa donire gbogbo.Ifa ni ọna eleyii yio la to o donire gbogbo, loju Irẹtẹ Meji ni Ifa…Ifa… ifa na sọ bẹẹ, loju Irẹtẹ Meji. Bẹẹ ni
.Irẹtẹ Meji 4:
Ifa ni keleyii, ko tun na ẹkọ tifa tun… lodu Eji Ẹlẹmẹrẹ naa tun pe. Ifa ni keleyii, ko lọ ronu sọrọ igbesi aiye rẹ daadaa, ko si ma huwa re. Koma ba eniyan ditẹ o, ko ma ba eni di coup o. Ki…ki ile aiye rẹ o le ba dun, ko le ba la rinrin o. Ifa ni ti o ba ti ditẹ mọ eniyan, Ifa ni nkan re o si dun titi dọjọ alẹ ni. Tọran o gun ti o ko. Loju Eji Ẹlẹmẹrẹ. Ifa sọ bẹẹ. Keleyii o ma ditẹ mọ yan o. Lagbaja, a ni fi ṣe senator, tamọdu a ni fi ṣe aareorilẹ ede, ko ma ba wọn si nibi ti n ṣe iru ẹ rara rara. Keleyii yio le ba ni isimi, ko le ba ni lọ siwaju. Lodu Irẹtẹ Meji, ni Ifa na ti sọ bẹẹ. Ko le ba ni lọ siwaju, ko jẹ ki inu rẹ o plain, ko ninu kan, ko ni iwa re. Ifa ni yio si…yio si… yio lẹwa titiọjọ alẹ ni. Ẹwa rẹ… ẹwa rẹ yio si wa, yio ba kalẹ ni. Iwa rẹ yio ba kalẹ ni. Gbogbo nkan rẹ yio ma gun ni, ko ni ri idaamu kankan, ti o ba ti ninu meji sọ mọnikeji. Bẹẹ ni Ifa sọ bẹẹ. Nibi Ifa gba to fi sọ bẹẹ re o. Ifa na wipe:Okiti bamba ni pẹkun opopo a difa fun Alagan a bu fun Eṣu. Labalaba nikan ni bẹ lẹhin ti n ṣẹbọ. O ni ẹ wonu mi ẹ wẹhin mi, Labalaba o mọ lọtẹ ninu. Ẹ wọnu mi ẹ wẹhin mi. Labalaba o mọ lọtẹ ninu.Ifa ni… la ni labalaba hun wi doni. Ti labalaba ba n fo lọ. Butterfly, when it is fly[ing], ẹ wọnu mi, ẹ wẹhin mi. Labalaba o mọ lọtẹ ninu. Ẹ wọnu mi, ẹwẹhin mi, na lo jẹ labalaba ẹ ri pọ rẹwa. Ẹyẹ to rẹwa ni. Bẹ ba ri ati ọsan [ati oru] to ti o ba fo bayii, a ni ẹ wọnu mi, ẹ wẹhin mi, emi o lọtẹ [ni]nu. N lo jẹ o rẹwa titi. Ifa ni teleyii o ba ti ditẹ mọ yan, aṣeyọri nbẹ fun dọjọ alẹ. Ifa na lo sọ bẹẹ loju Eji Ẹlẹmẹrẹ. Abọru aboye o. Tifa wi…tifasọ fun eleyii nu un, loju Eji Ẹlẹmẹrẹ.Irẹtẹ Meji 1:Irẹtẹ Meji has come up for this person. Ifa says (s)he should offer a sacrifice and be dilligent in his/her work. Ifa predicts success for him/her. (S)He should not be lazy, but work hard and concerntrate on his/her work so that everyone knows what kind of work (s)he does. This is so that (s)he does not bring disrepute to his/her name because if people do not know what kind of work (s)he does, (s)he may loose that good name. Ifa says so. Ifa says the work that this person makes a priority, people should know it, so that (s)he may maintain a good name throughout his/her life. If (s)he is a mechanic, people should know that (s)he is a mechanic. If he is a babalawo, people should know that he isa babalawo. If (s)he is a driver, people should know that (s)he is a driver. Ifa says then it will be well with him/her, but if they don’t know whathis/her pofession is, they will say, “What kind of work does (s)he do?” Ifa says that this person should not bring disrepute to his/her name or the name of his/her father. (S)He should make his/her profession a priority so that (s)he will beblessed until the end of his/her days. Ifa says so in Eji Ẹlẹmẹrẹ, which is another name for Irẹtẹ Meji. This is how Ifa arrived at that conclusion. Ifa said,Ẹẹrun n yan foto kete a difa fun Atọka eyi ti ṣe Ilari Eledumare. Ilari o ba roko, emi iba ṣe Ilari Ifa. Emi iba ma yọ ṣẹṣẹṣẹ. Ero Ẹpo, ero Ọffa, Ilari o ba roko emi iba ṣe Ilari Ifa. Ta ni o mọ pe Ilari Ifa lemi ṣe?[Ẹẹrun n yan foto kete cast Ifa for Atọka (a special type of bird) who was the servant of God. If the servant leaves, I will take the role of Ifa’s servant. I would rejoice at my good fortune.Listen everyone, if the servant leaves, I will become the servant of Ifa. Who does not know that I am the servant of Ifa?]Now, I am a babalawo. Everyone knows that I am a babalawo. I will tell anyone, “I am a babalawo. I am Chief Ifarinwale the High Priest of Ifa in Modakẹkẹ. Deji is a student from America. Professor Ajibade is a professor at Obafẹmi Awolọwọ University.” Everyone knows what his/her preferred job is. Ifa says everyone should know this person’s profession, so that his/her name does not fall into disrepute. Ifa says so for this person, that (s)he should apply him/herself to his/her work. Yes, Ifa says so in Eji Ẹlẹmẹrẹ.Irẹtẹ Meji 2:Ifa also says for this person that (s)he should make a sacrifice for three children of the same mother so that when things are going well for one, it can be so for the others as well. (S)He should make a sacrifice, so that all of them maybe successful together. This is what Ifa says in Eji Ẹlẹmẹrẹ. When one of the younger siblings isrich, the other is poor. Ifa says (s)he should offer a sacrifice so that they may all become rich at the same time. Yes, this is how Ifa said it. Ifa said:Ajalu yeke awo omi ni ṣawo omi. Ajalu pẹtẹ awoẹrẹ ni ṣawo ẹrẹ. Ajalu sorosan lo difa fun kankan eni ti n re aiye ainiku. Won ni ki awon mẹtẹẹta o rubọ. Ọmọ iya kan naa ni wọn. Omi, ọ gbọ riru, o ru o; o gbọ titu, o tu. Ko pẹ, ko jinna, Ifa wa ba larin iṣẹgun. Kankan gbọ riru, o ru o; o gbọ titu, o tu. Ko pẹ, ko jinna, Ifa wa ba larin iṣẹgun. Ẹẹrẹ nikan ni n bẹ lẹhin ti o rubọ.[Ajalu yeke the priest of water divined for water. Alaju pẹtẹ the priest of mud divined for mud. Ajalu sorosan is the one who cast Ifa for the sponge, the one who went to the place of immortal life. The ifa priests said that all three of them should offer a sacrifice. They were all children of the same mother. Water did everything asked of him. He offered the sacrifice, and not long after that, he was blessed. The sponge did everything asked of him, and not long after that, he too was blessed.Mud was the only one who did not offer the sacrifice]That is why it has never been easy for mud. If water is flowing like this, and someone comes to the river, the water will continue to flow. It willsay, “It is because I offered a sacrifice that I flow so easily teretetete. It is because I offered a sacrifice that I flow so easily teretetete. Water is straightforward and clean. If you wade into a river and kick up some dirt, it won’t take long forit to settle again. It is the sacrifice that water made that allows it to stay clean and proper likethis. The sponge that people use to take a bath, if you are washing yourself and flick it like this, water will come out. It will say it offered a sacrifice so that it can be so clean ṣekeṣekeṣeke, that is what the sponge says. Mud’s failure to offer a sacrifice resulted in its dirtiness. If you put your foot in it, it will stick to your foot madimadi. So that his/her life will not come to an abrupt end, Ifa says that this personshould offer a sacrifice so that it may be well with all three siblings. Ifa says so in Eji Ẹlẹmẹrẹ.Irẹtẹ Meji 3:Ifa also says for this person cannot find work orescape his/her current suffering, but if (s)he gets initiated into Ifa, his/her problem will be resolved. Ifa says this person’s problem has no solution. (S)he cannot find a way to break through or a way out. (S)he works, but does not find any way to breakthrough, (s)he also tries various businesses but always operates at a loss. (S)he makes no profit. Ifa says this personshould get initiated into Ifa; (s)he is in the midstof enemies, and they will not allow him/her to become rich. This is what (s)he should do so that a change may take place. Ifa says so. Ifa says:Poro bayii, ala bayii a difa fun Irẹ ti o tẹ meji ti o si la gudugudu. Wọn ni ki Irẹ, wọn ni o lọ, ko lọ tẹfa, ko le ba la, ko le ba ni lari. Ki wahala rẹ o le ba dopin. Irẹ ma gbọ, o mọ ru, o lọ tẹfa. Lọrọ rẹ ba gun, lo ba ko. Ni gbogbo ayipada ba de si iṣẹ aje rẹ. Bo ṣe la nu. To lowo, hmm. Ni n ba yin awọn awo, lawọn awo wa n yin Ifa. Ijo ni n jo, ayọ ni n yọ, ẹsẹ tọ na fa bayii. Ni ijo bọ si lẹsẹ, torin awo ko si lẹnu. O ni bẹẹ babalawo toun [wi]bẹẹ, babalawo toun sọ. Poro bayii ala bayi a difafun Irẹ ti o tẹ meji ti o si la gudugudu. Asẹhin waasẹhin bọ, igba Irẹ tẹ meji lo wa la gudugudu. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igba Irẹ tẹ meji lo wa dalaya. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igba Irẹ tẹ meji lo wa da alabiamọ. Asẹhin wa, asẹhin bọ, igba Irẹ wa tẹ meji lo wa donire gbogbo.[
Keep your furrows within your boundaries cast Ifa for Cricket, who received Odu Irẹtẹ Meji and became very successful. Cricket was told to getinitiated into Ifa so that he could become successful. So that his problems might come toan end. Cricket took the advice, offered the sacrifice and got initiated into Ifa. His problem was resolved and everything fell into place. A drastic change took place in his business. That is how he became wealthy. He praised his babalawo, and the balawo in turn praised Ifa. Hedanced and rejoiced, moving his legs like this. Cricket just began to dance and sang the song of the babalawo. He said, my babalawo said so, he told me so. Keep your furrows within your boundaries cast Ifa for Cricket, who received Odu Irẹtẹ Meji and became very successful. Notlong after this, when Cricket received Irẹtẹ Meji he became wealthy. Not long after this when Cricket received Irẹtẹ Meji, he gained wives. Notlong after this, when Cricket received Irẹtẹ Meji, he became a parent. Not long after this, when Cricket received Irẹtẹ Meji, he received all kinds of blessings.]Ifa says the way to this person’s blessings will open up in Irẹtẹ Meji. Yes.Irẹtẹ Meji 4:The lesson Ifa teaches in Eji Ẹlẹmẹrẹ is that thisperson should think carefully about his/her life and behave well. (S)he should not join those who conspire against others. This is so (s)he may have an enjoyable and pleasant life. Ifa says that if (s)he doesn’t make evil plans toward another person, life will be pleasant for him/her until the end of his/her days. His/her problems will be resolved. Ifa says so in Eji Ẹlẹmẹrẹ. This person should not conspire against others. If people are saying “This person should not become senator, and that person should not become president,” (s)he should not join them in what they are doing at all so that (s)he may have peace and progress in his/her life. This is what Ifa says in Eji Ẹlẹmẹrẹ. So (s)he can move forward, so that (s)he may have singleness of mind, (s)he should be straightforward and upstanding. Ifa says (s)he will possess beauty until the end of his/her days. That beauty will stay with him/her to the end of his/her days. Everything will be successful, and (s)he will not have to struggle, if (s)he is not duplicitous with anyone. This is how Ifa said it. Ifa said:Okiti bamba ni pẹkun opopo a difa fun Alagan a bu fun Eṣu. Labalaba nikan ni bẹ lẹhin ti n ṣẹbọ. O ni ẹ wonu mi ẹ wẹhin mi, Labalaba o mọ lọtẹ ninu. Ẹ wọnu mi ẹ wẹhin mi. Labalaba o mọ lọtẹ ninu.[A large bank is at the end of the road cast Ifa for Alagan consulted Ifa for Eṣu. Butterfly is the one who stayed behind to offer a sacrifice. He said, look at my front, look at my back. There is no evil inside the Butterfly. Look at my front, look at my back. There is no evil inside the Butterfly.]This is what the butterfly says up until now. If a butterfly flies, it says “look at my front, look at my back. I have no evil inside me. Look at my front, look at my back.” That is how the butterfly is so beautiful. It is a beautiful creature. If you see it at anytime, if it is flying like this, it is saying, “look at my front, look at my back. I haveno evil inside me. It is so beautiful! Ifa says if this person does not conspire against others, (s)he will have success until the twilight of his/her life. Ifa says so in Eji Ẹlẹmẹrẹ.



No comments:

Post a Comment

Note: Only a member of this blog may post a comment.

Featured post

Work-Life Balance - How to Protect Your Boundaries When Your Company Is Struggling - Sun and Planets Spirituality AYINRIN

 Work-Life Balance -  How to Protect Your Boundaries When Your Company Is Struggling - Sun and Planets Spirituality AYINRIN HBR Staff/Unspla...