Interpretation of Sixteen major odu ifa (oju odu m erindinlogun) part 2 posted by admin.

ODU IFA IROSUN MEJI
       I I
       I I
      II II
      II II
Irosun Meji 1:

Eni ti Ifa Irosun Meji to ba jade si, ta ba da fun eniyan, Ifa ni keleyii un o rubọ o nitori iku, kemi rẹ o le baa gun. Ifa ni ko bọfa fun un, ko fọgẹdẹ agbagba, ko fi bọfa fun un. Ifa loun gba eleyii unkale lọwọ iku. Oun o gbale lọwọ aarun, oun gbale lọwọ ofo, lodu… eni ti iru Ifa Irosun Meji ba jade si Ifa ba gbe e. Ifa na ni ko rubọ nitori emi gigun. Bẹẹ ni ibi tifa gba tifa fi sọ bẹẹ ni o:Irosun Meji owo oloko o to na a dia fun Ọrunmila baba fi ọgẹdẹ agbagba gbọmọ rẹ kale lọwọku. Ifa ni gbigbani o gba mi o, ọgẹdẹ agbagba kii gboloko ti. Ọrunmila gbigba ni o gbami.Ifa na sọ bẹẹ lodu Irosun Meji. Ti Irosun Meji ba jade bayii, Ifa na sọ bẹẹ, pe keleyii o rubọ nitori iku ni o. Eni Irosun Meji ba ti jade si, Ifa lemi re osi gun. Wọn ni, nigba tỌrunmila, o sun nijọ na, loba ri nkan apẹrẹ, o lala. Lo ba ke si awọn awo jọ,gbe ki wọn dafa fun oun. Nan ba dafa, wọn ni, Ah, Baba! Ẹ rubọ nitori iku la wọn wo ni okan yi. Ifa ni kẹ fi ọgẹdẹ agbagba kẹ fi.. kẹ…kẹ fọgẹdẹ agbagba ni ẹ gunyan. To…to di eku ẹja si, ti ẹ bọ Ifa. Ifa na pe oun gba eleyii un kale lọwọ iku. Oun o gbale lọ. Bo ṣe rubọ nu un. Ogun ba ṣe, bẹẹ ni Irosun Meji sọ bẹẹ.
Irosun Meji 2:
Odu  Irosun Meji, eni tIfa naa ba toun jade si, Ifani iṣẹ teleyii un ṣe ko rere nbẹ, ko jere. Iṣẹ rẹ o lọ siwaju. Iṣẹ o lọ dede. Gbogbo nkan polukurumusu ma lọwọ. Ifa ni ko, ko bẹgbẹpe. Ifa ni eleyii un o bẹgbẹpe. Bo ba gbawin ọja, ko ni rowo rẹ san, ko ni roju owo de ibi pe o ri, yio rire nbẹ. Ṣugbọn Ifa ni teleyii un to ba ti rubọ, ogun agbana, lo kuro nwaju ẹ, yio ri ita jẹsẹ, yio rowo na, to nolowo, to jo, ti o yo, jẹ pe abadi olowo si. Ti o dolowo gan. Suddenly la ba di olowo si. Ti… ti o ni gbagbe towo na wa gba kalẹ. Bi loju Irosun Meji o. Bi to gba to fi sọ bẹẹ ni o:Ada nko ada roko, ada nko, a da rodo, ada wa mo foro a dia fun Ẹlẹkọ Idanre eyi ti o lọrọ kọjọ ale o to lẹ. Ifa ma mọ jẹ kọrọ ale temi o lẹmi. Ifa ma jẹ kọrọ alẹ tẹmi Ifarinwale Ogundiran, ma jẹ [ki] o lẹmi ti n o lowo lọwọ.Na ba ni, Ẹlẹkọ Idanre, ẹkọ ni mama yi maa n su.Ilu kan ni njẹ Idanre ni Naijiriya nbii. So mama yi,to ba ba lọ gbawin igbado to fi n ṣe ẹkọ, yio sọ fun igbado pe, nigboun ba ṣe ẹkọ yi tan o, toun ba ta a tan, loun o wa fun un lọwọ o. Nigbo o ba tẹkọ tan, ko tun ni roju owo san fun onigbado, ṣeeni ti [k]o rowo san fun igbado ni o rowo jẹun, ni o rowo bẹgbẹpe. Ah! Titititi, o sa n jẹ gbese kakiri . Bo yọdọ gba nigbbo ti… yio gbawin lọdọ eleyii. Nigbo to ba ti ya oju oti yio tun lọ bi mi[iran] ko ni rowo san, yio tun lọ… O wa…Ọrọ rẹ yio ba ni bo lọrọ oun wa ṣe wa n ri yii. Lo ba mejikẹta, o darunun, lo ba gboko awo lọ. Lo ba lọ dafa, awọn babalawo ni ko rubọ. Gbogbo ohun toju rẹ n ri yi yio ṣẹgun rẹ, ti o si di eni ti o lowo lọwọ. Abadi gan ni o lowo si towo naa ba kalẹ.Ah! Gbogbo ohun ti o sa yanan lẹbọ, pe ko ru, o lẹiyẹle mẹrin, o ni giripo ooko nbẹ, o lẹwurẹ n lẹbọ. O ṣa ṣe gbogbo ohun tan ni [ki] o ṣe… Nigba ti wọn ṣe etutu fun tan awọn babalawo wa ṣefa fun un, wọn ni, owo Ifa o, da o, ko sanwo Ifa o. Wọn o sọye kan, ṣugbọn kan ni ko sanwo Ifa. O ni, ah, oun [k]o ti ri owo. Awọn babalawo sa n lọ sinin lowo. Oun [k]o ti n jere ninu ọja toun ta, oun o rere nbẹ, wọn ni o da. A nlọ oko awo, ka wọn to dari de, ko ti wa owo wọn ilẹ o. O loun o ti walẹ. Nan ni ah, iwọ Ẹlẹkọ Idanre, ṣe bo ni o [k]o jere, ni o ti n, ṣe bi o rubọ, ẹbọ rẹ fin. O ni oun [k]o ti rere nbẹ ni, ṣugbọn oun wa owo yin lẹ nigba tẹ ba fi de. Na babalawo ba lọ, nigba [awọn] babalawo tan fi dari de lẹhin oṣu mẹta, Ẹlẹko Idanre ti lowo. O ti di eni ti… ti…ti n fi aran, aṣọ aran ti n fi ṣe ipele. Ah! Nan pe aṣọ aran lo, lo gba yu lati jọ to, to lowo lori, aṣọ olowo ni. Olowo ni wọ. O ti fi ṣe ipele... Yio fapoti joko le kẹnka lẹgbẹ o ogiri bayii. Eni ti n ṣe agbọn ẹkọ kan ti o ta tẹlẹ, o ti n ṣe, basket bi mẹwa. Ẹkọ, agbọn ẹ kan bi mẹwa, oti n ṣe, ti n ta tan. Ah! Bawo ṣe de bayii lo si rowowọn san o si fun wọn lowo. Na[wọn] babalawo ni, babalawo toun [wi] bẹẹ, babalawo toun sọ:Ada nko a da roko, ada nko, ada rodo, ada wa mo foro a dia fun Ẹlẹko Idanre eyi ti o lọrọ kọjọ ale o to lẹ. Ifa ma mọ jẹ kọrọ ale tẹmi o lẹ mi.O n ṣẸlẹkọ Idanre ṣe bo o lo jere,Ẹlẹkọ Idanre ṣe bo o lo jere.O rubọ, o fin, o faran ṣe ipele, a wa fapoti joko ni kẹnka, lẹgbẹ ogiri,Ẹlẹkọ Idanre ṣe bo o lo jere,wọn ṣe Ẹlẹkọ Idanre, ṣe bo o lo jere ni.Ah, o ni ngba toun o ri owo yii na lo san yii. Ifa nilabadi nire eleyii un o de ti o si ni lari nbẹ. Lodu Irosun Meji o. Ifa ni keleyii o rubọ o la da nbẹ o, Ifa ni yio la o. Irosun Meji lo sọ bahun.
Translation
Irosun Meji 1:
Anyone for whom Irosun Meji is cast, Ifa says that person should offer a sacrifice because of death so (s)he may have a long life. Ifa says (s)he should worship Ifa. (S)He should use plantain in a sacrifice to Ifa. Ifa says it will deliver him/her from death. Ifa will deliver him/her from disease and loss if Irosun Meji comes up. Ifa says (s)he should offer a sacrifice to ensure long life. This is how Ifa explained it:Irosun Meji owo oloko o to na a dia fun Ọrunmila baba fi ọgẹdẹ agbagba gbọmọ rẹ kale lọwọku. Ifa ni gbigbani o gba mi o, ọgẹdẹ agbagba kii gboloko ti. Ọrunmila gbigba ni o gbami.[Irosun Meji the money of the farmer is not enough explains the case of Ọrunmila, who used plantains to deliver his child from the hands of Death. Ifa, please deliver me, plantainswill never fail the farmer. Ọrunmila] please deliver me.This is what Ifa says in Irosun Meji. If Irosun Meji is cast, Ifa says this person should offer a sacrifice because of death. Ifa says whoever has Irosun Meji cast for him/her can have a long life. We are told that when Ọrunmila was sleeping one day, he had a dream. He called together the babalawo to consult Ifa. They consulted Ifa and said, Baba! The dream means that you should offer a sacrifice because of death? Ifa says you should use plantains in the sacrifice. You should also use fish and rats to worship Ifa. Ifa says it will deliver this person from the hands of Death. That is how the sacrifice should be performed. The conflict wasovercome. This is what Irosun Meji says.
Irosun Meji 2:
In Irosun Meji, for anyone that Irosun Meji is cast, Ifa says that person is not having economic success. His/her business is not moving forward. Work is not going well. Everything is falling apart fo him/her. Ifa says (s)he is not living up to expectations. If (s)he tries to do business on credit, (s)he can’t make enough money to pay off the debt, (s)he won’t even make enough money to break even. But Ifasays if that person offers a sacrifice, the fight with poverty will be overcome, (s)he will begin to make progress, make money, and become rich. (S)he will become very rich. (S)he will become so rich that (s)he will dance and rejoice. (S)he will become rich in an astonishingfashion. It will happen suddenly, and (s)he will forget his/her problems when the money delivers him/her This is how Ifa explained it:Ada nko a da roko, a da nko, a da rodo, ada wa mo foro a dia fun Ẹlẹkọ Idanre eyi ti o lọrọ kọjọ ale o to lẹ. Ifa ma mọ jẹ kọrọ ale temi o lẹ mi. Ifama jẹ kọrọ alẹ tẹmi Ifarinwale Ogundiran, ma jẹ [ki] o lẹ nti o lowo lọwọ.[Where is cutlass? It has gone to the farm. Where is cutlass? It has gone to the river. Ada wa mo foro helps us to understand the case of the Ẹkọ (corn pap) seller of Idanre who was destined to have a success in the latter part of her life. Ifa don’t allow the latter part of my life to be hard. Ifa don’t allow me (Ifarinwale Ogundiran) to be poor in the twilight of my life]It is said that this ẹlẹkọ Idanre, she used to package and sell ẹkọ [corn pap]. Idanre is a town in Nigeria. So this woman when she bought corn on credit to make ẹkọ, she would tell the owner of the corn, “When I’m done preparing the ẹkọ and I have finished selling it, Iwill pay you back.” When she had finished selling ẹkọ, she hadn’t made enough money to repay the owner of the corn. Can a person who can’t pay her debt to her creditors find money tobuy food? Can she live up to her potential? Ah! She was building up debt everywhere. This is how she would do it, she would borrow corn on credit from this person. Then she would be too ashamed to come back to him/her and would run off to borrow from someone else. She wondered, “how did my problem become this serious?” She put two and two together and went to consult a babalawo. The babalawos cat Ifa for her, the babalawos said she should offer a sacrifice. They said everything that she is experiencing, she will overcome and become a very rich person indeed. She will become rich ina very curious way, and her money will last her alifetime.Ah! Everything that Ifa prescribed for the sacrifice, 4 pigeons, a large he-goat, and a she-goat, she offered them as a sacrifice. Whenthey [the babalawos] had finished their work, they said, “Where is our money? Please you must pay a fee for out services.” They didn’t demand a price, but they said she should offer them something. She said, “Ah! I don’t have any money.” The babalawos continued to ask for payment. She hadn’t made any profit from the ẹkọ that she had been selling. They said, “Ok. We are going off to do the work of Ifa. Before we come back, have our money ready!” She saidshe didn’t have the money ready. They said, “Ah!See this woman, you say you don’t have money. Wasn’t you sacrifice offered, and wasn’t it accepted?” She said, “I haven’t made any money, but I will have your money ready by the time you return. Then the babalawos left, and when they came back after 3 months, Ẹlẹko Idanre had become rich! She had the most expensive clothes made out of very rich material. Ah! They said ??? these are the clothesof a rich person. Rich people are the ones who wear them. She used the fabric to make costly clothing. She posed elegantly on a stool next to the wall like this. Someone who striggled to sell one bascket of ẹkọ before, she is selling ten basckets now. Even with ten baskets, she wouldrun out of ẹkọ to sell. Ah! This is how she came into the money she used to pay them. The babalawos said, it is as the babalawos said, it isas the babalawos predicted:Ada nko a da roko, ada nko, ada rodo, ada wa mo foro a dia fun Ẹlẹko Idanre eyi ti o lọrọ kọjọ ale o to lẹ. Ifa ma mọ jẹ kọrọ ale tẹmi o lẹ mi.[Where is cutlass? It has gone to the farm. Where is cutlass? It has gone to the river. Ada wa mo foro helps us to understand the case of the Ẹkọ seller of Idanre who was destined to have a success in the latter part of her life. Ifa don’t allow the latter part of my life to be hard.]They sang, “Ẹlẹkọ Idanre how did you make all of this money?Ẹlẹkọ Idanre how did you make all of this money?She offered a sacrifice, it was accepted, she used expensive cloth to make fancy clothing, she posed elegantly on a stool next to the wall.Ẹlẹkọ Idanre how did you make all of this money?Ẹlẹkọ Idanre how did you make all of this money?Ah! She said, when she made this money, she repaid her debt. Ifa says this person’s blessingswill come in a very curious way and (s)he will become rich in Odu Irosun Meji. Ifa says this person should offer a sacrifice, for the sign that is cast here. Ifa says (s)he will be successful. Irosun Meji says so.
ODU IFA OWONRIN MEJI
               II II
               II II
                I  I
                I  I
Ọwọnrin Meji 1:
Ni odu Ọwọnrin Meji ta ba da fun eniyan, Ifa sọ wipe keleyun, o ko san gbese to jẹ awọn ẹgbẹrun rẹ, kan le ba jẹ onilari. Ifa ni nkan [k]o lọdede fun eleyun, ko, ko lọ dede o! O si jẹ awọn ẹgbẹrun, ẹgbẹrun rẹ, o jẹ wọn lowo, ti [k]o ba san an, ko le ni lari kan. Bo ṣiṣe ko le roju tu ẹ. Ko si gbogbo ohun ti o ṣe ti o roju tu gbogbo nkan o kan polukurumuṣu mọ lọwọ ni. Lodu Ọwọnrin Meji. Ngbeleyun ba to san gbese to jẹ ẹgbẹrun rẹ, ni o to rowo, ni o to ni lari, ni o to jẹ tio ṣẹku. Ibi ti Ifa gba to fi sọ bẹẹ nii o. Ifa na sọ pe:Igba eeṣe to waja, ija ni o jẹ ki oun o waja, awo eeṣe to waja, ija ni o jẹ ki wọn o waja, ija ni o jẹ ki wọn o waja lo difa fun wọn lode Ọwọnrin nibi wọn ti n ja tori ẹẹdẹgbẹjọ owo ẹyọ.Wọn ni ki eleyun o rubọ. Ẹdẹgbejowo lo jẹ ẹgbẹrun rẹ un. Igba to, to ṣetutu, o wa si rubọ , wọn san ẹdẹgbejo, bi nkan si, bi nkan si “change” fun eleyun. Ifa ni ko pada fun un to n… ti o ti… loju Ọwọnrin Meji.Ọwọnrin Meji 2:Ifa si sọ fun eleyun naa, pe ko ṣetutu, ọrọ aje rẹ yio da. Koda boọjẹ inu kọrọ yara ni ti n ta ọja, wọn o wa mọ ba… wọn o wa bẹ, tan wa mọra nibẹ. Ti o si lowo, to ba ti le ṣetutu. Bo ba fi owo kekere bẹrẹ bayii, Ifa lowo kekere yio d… ko ni pare mọ lọwọ, yio di ninla. Bo… owo kekere, bo fi… 500 Naira to fi bẹrẹ owo, 500 Naira un, ko ni pare, yio di billion. Ti oun naa yio di olowo, Ifa sọbẹẹ. Ifa ni… ko rubọ. Ifa ni yio ni lari. Bi Ifa gba tofi sọ bẹẹ re o. O ni:Ọwọn owo laa pe [o]kan lowo mini, ọwọn ounjẹ laa pe niyan a difa fun eyi to wa ọmọba lẹhin ajori. Tewe tagba ni raja ẹyi to wọn, ẹ sare wa, ẹ waraja ọmọba.Ọmọba re, ọmọ ọba ilu kan ni. Lo ba gbiyanju, o lọ [si] ilu mii[ran]. Nigba ti ọrọ aje o ṣe dada. Nigba to dohun, ibi ti eniyan ba si kọkọ n de yio di ajoji. Bi ki eniyan gbera ni Naijiria niisiyi, ko lọ Amerika. Amerika ti o gbe ri tẹlẹ, yio kọkọ di ajoji nbẹ naa, kan to mọ ọ. Ngbo wa debẹ ti nkan o lọ dede, awọn babalawo dafa fun. Wọn niko rubọ o. Wọn ni, wọn o daamọ nibi, to jẹ pe yiosi ri tajẹ ṣe, bo si ti wulẹ kọja re o wọn to, wọn o maa ba ra a. Gbogbo n[kan] tan ni [k]o ṣe lẹbọ, loṣe lẹbọ. O si… o si… o ṣe bẹrẹ owo nuun. Eni to jẹ wipe to ba ri bi 10 Naira, ko ni tete fẹ na a. Yiomaa fi pamọ. Ah! Nna na ṣe pe ọwọn owo la pe o kan lowo mini. Itumọ ọwọn owo la pe kan lowo mini ni pe owo ti o pọ, ahh… tẹ, yio [eniyan yio rọra ma yio na] pe ngbo n ba na tan ni si bo lowo si ri mi i. Owo…owo la pe kan lowo mini nuun. Owonjẹ la pe niyan, ngba ti o ba ti si ounjẹ, ah! A ni iyan re.Bọ… bọ… bọ…bọmọba ṣe yii jẹ nuun. Lo ba di pe o mọyan, lo ba di pe awọn eniyan wa ba ra gbogbo ohun ti n ta. La, lo ba dolowo, lọmọba n jo, ni ba n yọ. Ni n, lo n yin awọn awo ti n ṣe Ifa fun un, lawọn awo tan ṣe Ifa fun un na wa n yin Ifa. O ni bẹẹ, babalawo toun wi bẹẹ, babalawo toun sọ:Ọwọ n wo la pe lowo mi ni, ọwọ n jẹ laa pe niyana difa fun eyi to wo ọmọba lẹhin ajọri o. Tewe tagba ni re jo yio wọn, ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.O ṣe sare wa, ẹ wa raja ọmọba oẸ sare wa, ẹ wa ra ọja ọmọba.Atewe atagba ni raja ẹyi to wọnẸ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.Ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba oẸ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.Atewe atagba ni raja ẹyi to wọnẸ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.Kia nan ba ra, wọn o ti ẹ pe o wọn mọ. Nigba ti ojẹ pe adura rẹ ti gba, ẹbọ ẹ ti fin, n[kan] to yio ta ni…ti yio ta ni Naira kan, ṣe ni n ta 10 Naira. Bowo ṣe de nuun. Ifa ni keleyi o rubọ, Ifa laiye yio yọnu si. T… t…. t… taje o bu lọdọ rẹ gan. Abọru abọye o. Ti Ọwọnrin Meji sọ nu o.
Translation
Owọnrin
 Meji 1:
In the Odu Ọwọnrin Meji, if it is cast for someone, Ifa says that person hasn’t paid his/her debt to the spirits in heaven, and as a result, (s)he cannot be successful. Ifa says things aren’t going well for that person at all. It is the spirits in heaven, it is their money. If (s)hedoes not pay it, (s)he cannot have any success. If (s)he doesn’t do it, (s)he won’t find a way to solve this problem. Everything that this person does or tries to deal with the situation, everything will turn to confusion in Ọwọnrin Meji. When this person pays his/her debt to the spirits in heaven, that is when (s)he will make money, will become successful, and will have great abundance. This is how Ifa explained it. Ifa says:Igba eeṣe to waja, ija ni o jẹ ki wọn waja, awo eeṣe to waja, ija ni o jẹ ki wọn waja, ija ni o jẹ ki wọn waja lo difa fun wọn lode Ọwọnrin nibi ti n ja tori ẹẹdẹgbejowo eyọ.[Calabash (implying an important person), why didn’t you come to the market? It is the war that prevented him from coming to the market. Priest, why didn’t you come to the market? It was the war that prevented him from coming to the market. Helps us to understand their case inỌwọnrin, the place where they fought because of 1,500 cowries (a great sum of money)]Ifa says that person should offer a sacrifice. Ẹdẹgbejowo is what I have been calling his/her ẹgbẹrun. When (s)he makes an offering and offers a sacrifice, and pays his/her Ẹdẹgbejowo,that is when things will begin to change for that person. Ifa says they will change for him/her in Ọwọnrin Meji.
Owọnrin Meji 2:
Ifa also says for that person that (s)he should make an offering, so that his/her business affairs will go well. Even if (s)he is selling his/her wares from the corner of his/her room, people will come there to buy from him/her. (S)he will make money, if (s)he offers a sacrifice. If (s)he starts the business just a littlemoney, Ifa says that money will neṣer disappear. If (s)he starts with say, 500 Naira, that 500 Naira cannot disappear, it will become a billion, and (s)he will become rich. Ifa says so.Ifa says (s)he should offer a sacrifice, and (s)hewill become successful. This is how Ifa explained it. Ifa says:Ọwọn owo laa pe lowo mini, ọwọn ounjẹ laa pe niyan a difa fun eyi to wa ọmọba lẹhin ajo ri. Tewe tagba ni raja ẹyi to wọn, ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.[A lack of money is what we call owo mini, a lack of food is what we call a drought, helps us to understand the case of the one who found the prince in a far away land. Both young and old don’t care how much it costs, hurry, come and buy from the prince!]This prince, he was the child of the king of a certain town. He tried his hand at business in another town when business was not going wellin his own town. Whenever someone first reaches a place, (s)he becomes a stranger there. If, for example, someone were to leave Nigeria now, if (s)he went to America where (s)he has never lived before, he will quickly become a stranger there as well before everyone gets to know him/her. When he got there and things were not going well, he went toa babalawo to consult Ifa for him. The babalawosaid that he should offer a sacrifice. He said theprince would be well-known, he will be successful to the extent that no matter how expensive his goods are, people will still buy them. He prepared everything he was instructedto include in the sacrifice. That is how he started to make money. He was someone who, if he had 10 naira, he wouldn’t want to spend it. He would save it. Ah! That is why they say, a lack of money is what we call owo mini. The meaning of, “a lack of money is what we call owo mini” is that when money is scarce… people will be very careful with it and will not want to spend it. They will think, if I spend all of this money, where will I find more? A lack of money, that is what we call owo mini. A lack of food is what we call a drought, when there is no food, ah! We say it is a drought.This is how the prince survived all of that. It got to the point that he could call people to buy what he was selling. He became wealthy. The prince danced and rejoiced. He praised the priests who consulted Ifa for him, and the priests in turn praised Ifa. He said, it is as the babalawo said to me, it is as the babalwo predicted:Ọwọn owo laa pe lowo mini, ọwọn ounjẹ laa pe niyan a difa fun eyi to wa ọmọba lẹhin ajo ri. Tewe tagba ni raja ẹyi to wọn, ẹ sare wa, ẹ wa raja ọmọba.[A lack of money is what we call owo mini, a lack of food is what we call a drought, helps us to understand the case of the one who found the prince in a far away land. Both young and old don’t care how much it costs, hurry, come and buy from the prince!]He sang: Hurry, come buy from the prince!Hurry, come buy from the prince!Both young and old, come buy this no matter how expensive!Hurry, come buy from the prince!Hurry, come buy from the prince!Hurry, come buy from the prince!Both young and old, come buy this no matter how expensive!They all rushed to buy from him and didn’t care how much he charged. Moreover, his prayers were answered, his sacrifice was accepted. Something he would sell for one Naira, he would sell for 10 Naira. That is how he came into his money. Ifa says this person should offer a sacrifice, and (s)he will be in the good graces of the spirits who own the world. (S)he will have an abundance of riches. That is what Ọwọnrin Meji says.
ODU IFA OBARA MEJI
       I I
      II II
      II II
      II II
Ọbara Meji 1:
Eni ti Ifa Ọbara Meji, to ba jade si, Ifa ni keleyun o rubọ o, ko si ṣọra, ko ma kanju kọja kadara tỌlọrun damọ. Ko ma pe ohun ti lagbaja ṣe, ẹmi o no ṣe o ko ma ba ko abamọ ti bẹbọ loju Ọbara Meji. Ifa ni eleyi gbọdọ ni suuru daadaa ko si gba gbogbo ohun ti Ọlọrun ba damọ, pe kadara ni. Ko ma fi ipa wowo o. Ko ma fipa sẹ n ti o fẹ ko ṣe o. Ifa ni ti o ba ti fipa wowo, to si tẹpa mọ iṣẹ rẹ ti n ṣiṣe ti si n gbadura, Ifa ni ngba to gba pe ibi Eledumare ba ni o de, yio de bẹ, loju ỌbaraMeji ni o! Nibi Ifa na gba to fi ti sọ bẹẹ ni o. Ifa tẹmọ eleyi lẹti daadaa. O ni:Ikanju o ṣe jaye. Wara wara o ṣe ju sapo. Gbogbo ohun tỌlọrun ba ṣe fun un ni laa gba a difa fun Eyin-titi-n-rin, eyi to ṣọmọ Eji Ọbara. Igbao ba ya Eyin-titi-n-rin a debi ọmọ re.Ifa nigba ti eleyun ba foriti iṣẹ rẹ to ni aforiti, ngbo ba ya oun naa, o jana, ti o ni lari. To jẹ pe lari na wa ba a, yio ba dọjọ alẹ. Ṣugbọn to ba lọ fipa wowo to lo na fẹ ṣogun owo, to fẹ ṣe bi lagbaja ṣeṣe, o fẹ ṣe bi tamọdu ṣeṣe, ini-ku-ni lo ku ti o ni o. Ṣugbọn to ba ti ni suuru, to gba kadara tỌlọrun damọ pe ah! Ngbo ba ya, Ifa ni yio da fun eleyun. Keleyun o ma kanju, ko ma kanju kọja kadara rẹ. Ifa sọ bẹẹ loju Ọbara Meji. O ni ko rubọ nbe. Bẹẹ ni Ifa sọ bẹẹ. Aboru aboye, loju Ọbara Meji.
Ọbara Meji 2:
Ifa na si tun kọ ni lẹkọ loju Ọbara Meji. O ni ire eleyii o…ọna rẹ yio la. Ifa ni ọna rẹ o la, tire rẹ o si tẹ lọwọ loju Ọbara Meji naa ni lo ti sọ bẹẹ. O ni eleyii yio… iyawo ti o fẹ, ti o fẹ, Ifa ni o… obinrin naa nigbo ba fẹ dele ni ọkunrin ni o kọ bifun un. Nibi Ifa na ti sọ pe ire eleyun o tẹ lọwọ nu. Ọkunrin naa ni o kọkọ bi fun un, ọmọ naa, o si ni lari ti o la. Toun gan to jẹ baba rẹ gan, o si ni lari. Ifa ni… adura rẹ yio gba, ko ṣetutu. Bẹẹ ni.Ni loju.. bẹẹ ni Eji Ọbara, lo ba n lọ ra… wọn ni kolọ ra ẹru obinrin o, lọja o. O si lọ ra ẹru obinrin. Nigbo mẹru dele, nigba ti o ti to bi oṣu meelo, o ri oyun ninu ọmọbinrin yii ah! Ere ni awa da ni. Ko sọrọ, ko binu, o sa n toju ẹ. Nigba ti obinrin yio bi, lo ba bimọ, lo ba bimọ ọkunrin. O si n tọju wọn, bi ṣe n tọju ọmọ, ni n t… ẹ ri pe ẹru to ra ti di meji, obinrin lo lọ ra jẹru obinrin lo lọ ra lọja, oni… Ifa ni eleyii, ire n bọ lọdọ rẹ kii ṣe ire kan mọ.Ire meji lo tun jẹ. Bi… bi ire Eji Ọbara ṣe di meji nu un. O…o ni iyawo, o… o lọmọ. Lọmọ ẹ ba dagba. Ni n ba ṣiṣẹ fun un. Lọmọ naa kọfa, ni n dafa, ni n pawo wale fun baba. Ni iya ọmọ naa ba duro daa. Ni baba naa lo lọ [lowo lọwọ]. Ni ban yin awọn babalawo, awọn babalawo wa n yin Ifa pe aiye yẹ oun bayii. Ohun ti babalawo sọ funun naa re pe ire oun yio toun lọwọ koun o ma kanju, pe aṣe ire ni o tun lọ… Lo ba bẹrẹ ọdun Ifa,nigba ti yio ṣe ọdun Ifa, o ni kawọn babalawo o boun pabi ko… pe toun tọpe toun tun ju ọpẹ lọ. Ni ba n yin awo, awọn awo wa n yinfa. Lo ni bẹẹ babalawo toun [wi] bẹẹ, babalawo toun sọ:Kukunduku lo tagbo mọlẹ o ni [ko] kọminu afẹrẹ a difa fun Eji Ọbara eyi to rẹru meji to yan ketekete. Eji Ọbara a fi gba wa rẹru meji to yan ketekete.O n ṣe:Eji Ọbara a fi gba wa rẹru meji to yan keteketeẸru ti mo ra nu lo la miẸru ti mo ra baba mo fi sinO n ṣe ẹru ti mo ra, baba mo fi sin oooẸru ti mo ra, baba mo fi sinẸru ti mo ra n lo la miẸru ti mo ra, baba mo fi sinẸyin o ri pe temi tọpẹ, tẹmi jọpẹ lọẸru ti mo ra, baba mo fi sin oooẸru ti mo ra, baba mo fi sinẸru ti mo ra n lọla miẸru ti mo ra, baba mo fi sin.Ni n ba n jo, ni n ba n yọ. Ni n… Ifa ni ki eleyii pe ire le ṣe tan ti o de, obinrin toun si fẹ fẹ, obinrin daadaa ni. Yio… yio lalubarika, t…tọmọ rẹ o lowo ti o no ni lo… tifokanbalẹ o wa fun un. Pe ko ma fẹ obinrin yio ba ifa [something you get for free] nbẹ. Loju Ọbara Meji. Ifa lalubarika wa nbẹ fun un, to ba si jobinrin naa ni, ọkọ to ni nbẹ o, ọkọ to tori ẹ dafa si un, alalubarika [connector] rẹ ni, ti Ọbara Meji ba ti jade si eleyi un. Bẹẹ ni. Abọru boye, loju Ọbara Meji.
Ọbara Meji 3:
Ni oju Ọbara Meji naa, [eniyan] tifa n ba tun jade si, Ifa ni eleyi un fẹ lo mule ibudo [refuge/abode]kan. Boya o fẹ loko ni o, lati lọ maa n ṣiṣẹ agbẹ o. Boya o fẹ ra ilẹ fun ilẹ-iṣẹ, “company” kan lo fẹdalẹ o. Ifa ni ko ṣetutu nitori ẹ, Ifa ni company naibẹ ni o ti la. Ti ọpọlọpọ eniyan yio tun la ni abẹ rẹ, toun gan o tun wa dọba nbẹ. Tan mọ pe, ah! Chief, baba, ọba ni. Ti awọn gbogbo ọpọlọpọ ti wọn o ma jẹ tan ma n mu, tan o ni lari. Ifa ni ki… bẹẹ ni ko lo ra a. Bẹẹ ni, nibi Ifa gba ti o fi [ti] sọ bẹẹ ni. O ni:O sẹ pẹlẹnjẹ ọwọ mi ọtun. Ọ rọ minijọ ọwọ mi osi. Abẹbẹ oje lo mu oju Ọlọja tutu ninini a difa fun Ọba Ado, Ejigbara ilẹkẹ nijọto rire ba wọn mulẹ ibudo. Ẹbọ nan ni o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ o rubọ. Ẹru Ẹpo, ẹru Ọffa, ẹ wa ba ni ni jẹbutu ire. Jẹbutu ire laa ba ni lẹsẹ ọbariṣa.O n ṣe ki lo ṣonibudo dọba?,Eji Ọbara, Ifa lo ṣonibudo dọba.Eji Ọbara, ki lo ṣonidubo dọba?Eji Ọbaraaa, ori lo ṣonibudo dọba.Ifa lori eleyun, keleyun o rubọ nbẹ, ko bọ ori rẹ. Ifa nibudo ti n lọ re mu. Ifa ni bẹẹ ni o ti la wa, ti wọn si sọ dọba nbẹ. Bẹẹ ni loju Ọbara Meji, tifa ti sọ bẹẹ. Abọru aboye o. Bẹẹ ni. Ifa sọ bẹẹ fun un ni Ọbara Meji
Translation .
Ọbara Meji 1:
Ifa says for any person for whom Ọbara Meji is cast, that (s)he should offer a sacrifice and be careful. (S)He should not try to push beyond what God has ordained for him/her. (S)He should not say, “So-and-so did this, I too will do it” so that (s)he doesn’t come to regret it later. Ifa says this person must be very patient and accept everything God gives him/her as fate. (S)He should not seek money by force. (S)He should not try to do it by force. Ifa says if (s)he doesn’t seek money by force, and works hard, and prays, Ifa says when (s)he accepts that the place Eledumare says (s)he will reach, (s)he willreach that place in Ọbara Meji. This is the way Ifa explained it. Ifa gives this person a serious warning. Ifa says:Ikanju o ṣe jaye. Wara wara o ṣe ju sapo. Gbogbo ohun tỌlọrun ba ṣe fun ni laa gba, a difafun Eyin-titi-n-rin, eyi to ṣọmọ Eji Ọbara. Igba o ba ya Eyin-titi-n-rin a debi ọmọ re.[You don’t enjoy life by rushing. There is no gainin hastiness. Everything that God gives us we accept explains the case of Eyin-titi-n-rin, the one who was the son of Eji Ọbara. When it was time, Eyin-titi-n-rin became his child]Ifa says when that person faces his/her work and perseveres, when the time comes, (s)he willfind the right path and he will be successful. Blessings will come find him/her and last until his/her old age. But if (s)he seeks money by force or makes medicine to make money, if (s)he tries to do as someone else has done, (s)he will only get trouble in return. But if (s)he has patience, if (s)he accepts the destiny God has created for him/her, when the time comes, Ifa says things will go well for this person. This person should not rush and that (s)he shouldn’t try to overstep his/her destiny. Ifa says so in Ọbara Meji. Ifa says (s)he should offer a sacrifice. Yes, Ifa says so.
Ọbara Meji 2:
Ifa also teaches a lesson in Ọbara Meji. Ifa saysthe path to success will open up for this person.Ifa says that this person will expereince his/her blessings in Ọbara Meji. That is what Ifa said. Ifa says this person… the wife he wants to marry, Ifa says… that woman, shortly after she enters his house, she will quickly give birth for him. That is how Ifa says he will experience his blessings. Both the man for whom the woman gave birth and the child himsefl/herself will be successful and have an open road. The child’s father himself will also be successful Ifa says, his prayers will be answered if he makes an offering. Yes.In Ọbara Meji, Eji Ọbara was told to go buy a female slave in the market. So he went and bought a female slave. When he brought her to his house, after she had been there for a few months, he noticed that she was pregnant! Ah! It is a blessing for us! He didn’t say anything, he didn’t get upset, he took good care of her. Whenthe woman gave birth, she gave birth to a boy. He took care of them, the son and the mother. He saw that his blessing had been doubled! Thewoman he had bought in the market… Ifa says that the blessing coming to this person isn’t only one blessing. It is a double blessing. That is how the blessing of Eji Ọbara became two. He had a wife, he also had a son. The child grewup and worked for him. The child studied Ifa, performed divination, and called priests to come to the house of his father. The mother was also an outstanding person. The father became wealthy The father praised the babalawo, the babalawo in turn praised Ifa, sying that his life was truly blessed. That is what the babalawo said to him about experiencing his blessings if he didn’t rush. He held his Ifa festival, and when he did, he called all of the babalawo to come celebrate with him and break kola nuts. He said he could never be grateful enough for all he had received. He praised the babalawo, and the babalawo in turn praised Ifa. He siad, “the babalawo told me it would be so, the babalawo said,”Kukunduku lo tagbo mọlẹ o ni [ko] kọminu afẹrẹ a difa fun Eji Ọbara eyi to rẹru meji to yan ketekete. Eji Ọbara a fi gba wa rẹru meji to yan ketekete.[Kukunduku has anchored its roots firmly into the ground and so the wind does not bother it cast Ifa for Eji Ọbara the one who bought two very wonderful servants]O n ṣe:Eji Ọbara a fi gba wa rẹru meji to yan keteketeẸru ti mo ra nu lo la miẸru ti mo ra baba mo fi sinO n ṣe ẹru ti mo ra, baba mo fi sin oooẸru ti mo ra, baba mo fi sinẸru ti mo ra n lo la miẸru ti mo ra, baba mo fi sinẸyin o ri pe temi tọpẹ, tẹmi jọpẹ lọẸru ti mo ra, baba mo fi sin oooẸru ti mo ra, baba mo fi sinẸru ti mo ra n lọla miẸru ti mo ra, baba mo fi sin.[Eji Ọbara who bought two very wonderful servantsThe servant that I bought paved the way for my successI praise you baba (Ifa) for the servant I boughtHe said, I praise you baba (Ifa) for the servant I boughtI praise you baba (Ifa) for the servant I boughtThe servant that I bought paved the way for my successI praise you baba (Ifa) for the servant I boughtYou will see that I cannot give enough thanks for the blessings I have receivedI praise you baba (Ifa) for the servant I boughtI praise you baba (Ifa) for the servant I boughtThe servant that I bought paved the way for my successI praise you baba (Ifa) for the servant I bought]He danced and rejoiced! Ifa says that the blessing wouldn’t be complete when it arrived. The woman the man wants to marry, she is a good woman. She will be bring blessings and favor with her. His child will become wealthy. They will have great peace of mind. Ifa says he should marry the woman and will receive a free,unexpected blessing in this case of Ọbara Meji. Ifa says there is a great blessing there for him, and if it is a woman, the man about whom she is consulting Ifa has blessings, if Ọbara Meji is cast for that person.
Ọbara Meji 3:
In Odu Ọbara Meji also, if this figure is cast for someone, Ifa says that person wants to start some kind of venture. Perhaps (s)he wants to go to the farm to work as a farmer. Perhaps (s)he wants to buy some land to set up a business or company. Ifa says (s)he should make an offering because of this desire. Ifa says that his/her venture will succeed in that place. Many people will benefit from serving under him/her and (s)he will become like a king there. They will say, “This is our chief, leader, or king!” All of the people they will eat, drink, and find success because of him/her. Ifa says (s)heshould buy the land [or undertake the desired venture]. Yes, this is how Ifa said it:O sẹ pẹlẹnjẹ ọwọ mi ọtun. Ọ rọ minijọ ọwọ mi osi. Abẹbẹ oje lo mu oju Ọlọja tutu ninini a difa fun Ọba Ado, Ejigbara ilẹkẹ nijọto rire ba wọn mulẹ ibudo. Ẹbọ nan ni o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ o rubọ. Ẹru Ẹpo, ẹru Ọffa, ẹ wa ba ni ni jẹbutu ire. Jẹbutu ire laa ba ni lẹsẹ ọbariṣa.O n ṣe ki lo ṣọnibudo dọba?Eji Ọbara, Ifa lo ṣonibudo dọba.Eji Ọbara, ki lo ṣonidubo dọba?Eji Ọbaraaa, ori lo ṣonibudo dọba.[If it is flexible to my right, if it is stiff to my left, the lead fan causes the face Ọlọja to be very cool cast Ifa the king of Ados, man of many titles when he was going to acquire a new estate. He followed the babalawo’s directions exactly. People from far and near, come meet me surrounded by blessings. An abundance of blessings is received at the feet of God.What makes the owner of the estate become a king, Eji Obara?Ifa/Eji Obara made him to be kingEji Obara, what makes the owner of the estate become a king?Eji Obara, his destiny (ori) is what makes the owner of the estate to become a king.]Ifa says this person should worship his/her ori [destiny]. Ifa says the estate that this person wants to acẹuire will grow and (s)he will become like a king. Yes, this is what Ọrunmila say.
This write up was compiled by  on Awo Rodriguez ifatomi an ifa apprentice under the tutelage of babalawo Obanifa.

No comments:

Post a Comment

Note: Only a member of this blog may post a comment.

Featured post

Work-Life Balance - How to Protect Your Boundaries When Your Company Is Struggling - Sun and Planets Spirituality AYINRIN

 Work-Life Balance -  How to Protect Your Boundaries When Your Company Is Struggling - Sun and Planets Spirituality AYINRIN HBR Staff/Unspla...