Interpretation of the sixteen major odu ifa (oju m erindinlogun put 3) posted by admin

This write up was compiled by omo Awo Rodriguez ifatomi an apprentice under the tutelage of babalawo Obanifa
ODU IFA OKANRAN MEJI
II II
II  II
II  II
 I   I I
Ọkanran Meji 1:

Eni ti… Loju Ifa Ọkanran Meji to tun wa nilẹ yii, tatun da yii, Ifa ni eleyii o ni awọn… aarin ọta lo wa.Obinrin kan nu un, o ni iṣoro nitori ọmọ, o si wa laarin ọta. Ifa nan si ti ro pin pe o le bimọ mọ. Ifani ko rubọ ko lọ bọ Ọṣun. Ifa ni yio bimọ. Gbogbo ọta to ro pin loju oti patapata. Ifa lo sọ bẹẹ, fun ọmọbinrin naa. Nibi Ifa na gba to fi [ti] sọ bẹẹ ni:Ki iwo kan mi kemi kan an. Akanla ni Ọkanran Meji kanra wọn a difa fun Ajibolomide eyi ti wọnni o lokun ọmọ ninu mọ. Tọmọ ṣe tan to wa kunnu bi yindinyindin n jẹ tiẹ si gun o, ile Ọṣun owa gbayin mọ.Ile Ọṣun o… Nigbo rubọ bọ Ọṣun, ile rẹ wa kun kẹkẹ fun ọmọ. Ifa ni yio bimọ pọ. Oju yio si ti awọn alaropin. Bẹẹ ni Ifa sọ bẹẹ fun…fun ọmọbinrin un, laarin un, loju Ọkanran Meji.
Ọkanran Meji 2:
Ifa na si tun sọ tẹ… Ọkanran Meji ba jade fun eniyan, laarin un. Ifa ni, keleyun ko lọ… ko lọ mura si, ko ṣetutu, ko ṣetutu gbogbo ohun ti oju rẹ n ri, ti n jẹ niya, gbogbo rẹ lọwọ rẹ yio to [will get what yo uare lacking]. Bẹẹ ni, Ifa ni gbogbo ohun ti n jẹ iya loju n ri, lọwọ rẹ yio to. Ifa ni eleyun, babalawo ni, ko lọ ṣe e… Ifa ni ko lo ṣe, ko lọ kọfa. Ifa ni Ifa… iṣẹ Ifa ni yio ṣe la. Loju Ọkanran Meji, keleyun o lọ kọfa, ko…ko tẹfa. Ifa ni yio ṣe la, ninu ọna rẹ nIfa, ni ko lọ kọ ọ. To ba si jẹ Musulumi ni, ko lọ kọ ṣe Alfa. Iṣe Alfa ni iṣẹ rẹ. To ba si jẹ ẹlẹsin Kristiani, iṣẹ pastor ni iṣẹ rẹ. Ifa n lọ sọ bẹẹ… Ifa n lọ sọ bẹẹ. O ni, “Ki iwo kan mi, kẹmi kọ ọ.” Nibi Ifa gba to fi ti sọ bẹẹ nu o. O ni:Ki iwo kan mi, kemi kan ọ, akanla lọkanran Meji kan ra wọn a difa fun Adeṣọkan nijọ ti n ti n kọle ọrun bọ wa kọle aiye. Ẹbọ ni wọn ni o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, o rubọ. Riru ẹbọ ni fin ti gbe ni. Aitete ru teṣu a da ladanu. Ko pẹ, ko jinna, Ifa waba ni laarin iṣẹgun, aarin iṣẹgun la ba ni lẹsẹ ọbariṣa.O n ṣe:Ki lemi o ṣe la n temiOwo n temi o ṣe la nifaIfa ni n o ṣe la ni temiOwo n temi o ṣe…Ifa ni eleyun, ko ba jọ babalawo ni, Ifa ni o ṣe la. Ko lọ kọfa nbẹ. To ba si jẹ musulumi ni, ko lọ kọ ṣe Alfa. Iṣẹ Alfa ni o ṣe la nbẹ. Iṣẹ ti … Eledumaredamọ nu un, pe ko ma jiṣe fun eniyan. To ba si jẹ ẹlẹsin Kristiani ni, ko lọ ṣe… mura iṣẹ pastor. Ifa ni iṣẹ iranṣẹ lỌlọrun da pe ko maa toriṣe, iṣẹ atoriṣe ni. Ifa ni n ti eleyun o ṣe laanu o. Bẹẹ ni. Bẹẹ loju Ọkanran Meji, Ifa sọ bẹẹ.
Ọkanran Meji 3:
Ifa tun sọ bẹẹ tIfa ba tun gbe, to jade. Ifa ni ọmọbinrin kan nu; babalwo ni ko lọ fẹ o. Ti o ba fẹ babalawo, ti o le ba jawe ti o wa ẹgbo, ko ni bimọ o. Ifa ni tori ọmọ lo ṣe gbọdọ lo joko ti babalawo. To joko lefa. Ko lọ fẹ babalawo, ko lọ fẹ ẹ ko le jawe, to le wa ẹgbo, tori pe aarun inu nda laamu. O laarun inu! Bẹẹ ni. Ifa ni o laarun inu . Ifa ni, k…. babalawo ni ko… ko lọ sunmọ, ko fẹ babalawo. Ifa ni ko fẹ babalawo. Bẹẹ ni. O ni, nibi Ifa gba to fi tifa sọ bẹẹ:Oloju mọni nipo, aimọni lọffa, oju iri eni rere ka ma ki, a difa fun Nini, ọmọ ire lapa, ọmọ lanawọ kagun bi igba agogo. Nini dara, Nini ṣunwọn lejo. Aarun aibimọ ti n ṣolumọ lapa nkọ?Ifa pe a…aarun inu n de eleyun laamu, ko si jẹ o, ko fẹ jolokun ọmọ nu un. Ifa ni ko lọ… ko sunmọ babalawo, to le… tabẹ to le jawe ti o wa ẹgbo. Ifani igba naa ni yio to rọmọ bi. Ifa na sọ fun un. Ifalọmọ omi ni. Ọmọ omi ni. Ko si rubọ daadaa, ko mujọ tọṣun, ko si sunmọ babalawo, ko fẹ babalawo, ko le ba ri ọmọ bi. Ifa sọ bẹẹ loju Ọkanran Meji fun ọmọbinrin naa. Abọru aboye, tIfa sọ nu fun eleyun, abọru aboye o.Ọkanran Meji 1:In this Odu Ifa, Ọkanran Meji, that we have cast here, Ifa says that this person is in the middle ofenemies. It is a woman, and she is having difficulty bearing children; she is also in the middle of enemies. Ifa says they believe she will never be able to have a child Ifa says she should make a sacrifice and worship Ọṣun. Ifa says she will have a child. All of her enemies who doubted will be put to shame. Ifa says so for that woman. This is how Ifa said it:Ki iwo kan mi kemi kan an. Akanla ni Ọkanran Meji kanra wọn a difa fun Ajibolomide eyi ti wọnni o lokun ọmọ ninu mọ. Tọmọ ṣe tan to wa kunnu bi yindinyindin n jẹ tiẹ si gun o, ile Ọṣun owa gbayin mọ.[You reach out to me, I reach out to you. Ọkanran Meji reaches out by turns cast Ifa for Ajibolomide the one they said had no uterus. When the time came, it was discovered that her eggs were as numerous as those of ants, and her own case became clear-cut. Ọṣun’s house had no more room for children]When she worships Ọṣun, her house will quicklyfill up with children. Ifa says she will have many children. Those who doubted her will be put to shame. Yes, Ifa says so for that woman in Ọkanran MejiỌkanran Meji 2:If Ọkanran Meji comes out for someone, Ifa says that person should be careful and make anoffering. If (s)he makes an offering, everything that his/her eyes are seeing, all of the suffering, will be ended by his/her receiving what (s)he is lacking. Yes, Ifa says everything that is causing him/her suffering, that (s)he is experiencing, will be ressolved Ifa says this person is a babalawo. Ifa says he should go study Ifa. Ifa says the work of Ifa will open his road to success. In Ọkanran Meji, this person should study Ifa and get initiated into Ifa. Ifa says this will open his road to success, that this raod is inIfa, and he should study Ifa. If he is a Muslim, he should study to become an Alfa [Muslim cleric]. The work of an Alfa is his lot in life. If he is a Christian, he should become a pastor. Ifa says so. This is how Ifa said it:Ki iwo kan mi, kemi kan ọ, akanla lọkanran Meji kan ra wọn a difa fun Adeṣọkan nijọ ti n ti n kọle ọrun bọ wa kọle aiye. Ẹbọ ni wọn ni o ṣe, o si gbẹbọ nbẹ, o rubọ. Riru ẹbọ ni fin ti gbe ni. Aitete ru teṣu a da ladanu. Ko pẹ, ko jinna, Ifa waba ni laarin iṣẹgun, aarin iṣẹgun la ba ni lẹsẹ ọbariṣa.[You reach out to me, I reach out to you. Ọkanran Meji reaches out by turns cast Ifa for Adeṣokan on the day he was brought from heaven to earth. He prepared the sacrifice as instructed. He did everything asked of him. Failure to sacrifice to Esu in a timely manner renders the effort a waste. It did not take long, Ifa come see me enjoying the blessing of victory. The blessing of victory is received at the feet of the King of the gods.]O n ṣe:Ki lemi o ṣe la n temi?Owo n temi o ṣe la nifa.Ifa ni n o ṣe la ni temiOwo n temi o ṣe…[He said:What will I do to make my living?I will be successful with Ifa as my trade.It is Ifa will provide me with success in work.The trade for me is Ifa]Ifa says this person should do the work of a babalawo and that Ifa will open his road to success. He should study Ifa. If he is a Muslim, he should study to become an Alfa. It is in the work of an Alfa that his road will open up. That is the work that Eledumare [God Almighty] has ordained for him, and he should deliver His messages for people. If he is a Christian, he should prepare to be a pastor. Ifa says his work is that of God’s messenger that he should guideand counsel others. Ifa says that is what this person will do to become successful. Yes, this is the message in Ọkanran Meji.Ọkanran Meji 3:Ifa also says, if it carries this message, that there is one woman who should marry a babalawo. If she doesn’t marry a babalawo, one who can gather leaves and collect roots, she will not be able to have children. Ifa says she must stay in the house of a babalawo in order tohave children. She should be involved with Ifa. She should marry a babalawo who can gather leaves and collect roots because a sickness of the womb is causing her a greatl deal of suffering. She has a reproductive sickness! Yes.Ifa says she has this type of sickness. Ifa says that she should stay close to babalawo and marry one of them. Yes, this is how Ifa said it:Oloju mọni nipo, aimọni lọffa, oju iri eni rere ka ma ki, a difa fun Nini, ọmọ ire lapa, ọmọ lanawọ kagun bi igba agogo. Nini dara, Nini ṣunwọn lejo. Aarun aibimọ ti n ṣolumọ lapa nkọ?[At Ipo there are familiar faces, there are unfamiliar faces at Ọffa, the eye does not see a good person and refuse to greet him cast Ifa forNini the Ogun worshipper in Apa, powerful as the sounding of two hundred gongs. Nini is beatiful, and is awesome type of snake. What about the childlessness of Nini?]Ifa says that a sickness is causing this person agreat deal of suffering, that is preventing her from having fertilized eggs in her womb. Ifa says she should stay close to a babalawo who knows what leaves and roots to collect. It is at this time that she will have children. That is what Ifa says for her. Ifa says her children will be children of the water [of the river goddess]. Itwill be a child of water. She should make a sacrifice and venerate Ọṣun, stay close to babalawo, and marry a babalawo so that she will have children. Ifa says so in Odu Ọkanran Meji for the woman. This is what Ifa says for her.
ODU IFA OGUNDA MEJI
I I
I I
I I
II II
Ogunda Meji 1:
Ifa ni, eni ti Ifa Ogunda Meji to ba jade si, Ifa ni gbogbo ohun ti eleyii yio ba ṣe, ko ma beere lọwọ ori rẹ. Ifa ni ori ni kan lo le gbe debi ti n… ba n lọ. Keleyii o ma jijadun ara rẹ, ko ma pe boya nigba to n lowo, owo le ṣe e. Nigba to nipo kan, ipo le ṣe e. Keleyii o ko ronu ori, ko ronu bẹlẹda ṣe da a, ko ma pe oun ni agbara kan to leṣe e. Ko si agbara kan to ni lẹhin ori o! Bo ti wulepe, ko lowo to… ko… bo ba fẹ ṣe arẹ orilede, to fẹṣe president, ko bọ ori ẹ, ko beere lọwọ ori ẹ pe, n jẹ kini yii rọmọ ẹlẹda mi? Ki n to ṣe. Yio… ori yio sọ fun un. To ba rọmọ, ti o ba rọmọ tan ba nikeleyii o ma ṣe, ko ma ro poun lowo lọ o! Oun le ṣe e o! Ifa ni ko si ooṣa [oriṣa] ti da ni gbe lẹhin ori o. Bẹẹ ni Ifa sọ.Nigba ti gbogbo awọn ooṣa, nigba igbawasẹ, nigba [ti] awọn ooṣa wọnyii, wọn ni awọn lagbara, Oṣanla, oun ni o lagbara, oun le ṣe bi Eledumare. Ṣango loun le ṣe bi Eledumare. O ti gbagbe pe Eledumare lo da wọn. Ọrunmila naa naa ni, oun naa le ṣe bẹẹ. Wọn ni ko si eni to le ṣe bi Eledumare ninu yin. Wọn ni ori ni kan looṣa, to le ṣe bi Eledumare, nitori pe Eledumare da eniyan gẹgẹ bi awọnran ara rẹ, o si fi ori ṣe olori ohun gbogbo. Nna lori fi wa loke. Ori ni kanlo rubọ. Nigba igbawasẹ. Ifa ni keleyii… gbogbo ohun ti eleyii ba fẹ ṣe, iba jẹ fẹ ṣe arẹ orilede ni un, iba jẹ gomina ni o, iba jẹ si oko ni o ṣe ni o, iba je owo ni o, ko beere lọwọ ẹlẹda rẹ, ko to gbọna lọ. Wọn gbọ pe wọn taja nilu Oyinbo… ni Washington, ni goolu ti n ta. Ni Chicago, ni goolu ti n ta. Ko beere ko to ma gbọja lọ bẹ. Ti o ba bọri ẹ daadaa nbẹ ko beere lọwọ ori, yio kan ṣe lasan ni o. Ifa na lo sọ bẹẹ loju Ogunda Meji. Nibi Ifa gba ti Ifa fi [ti] sọ bẹẹ:Ọrunmila ni o dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ṣango loun talasan o ba rokun. Wọn ni ti Ṣango ba burinburin, to ba rin tititi, to de Koso, nile baba rẹ nkọ? Ti wọn fun un lorogbo ati akukọ adiẹ? Ṣango ni toun ba ti yo tan, o loun o pada nile oun ni. Wọn ni Ṣango o talasan o ba rokun.Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ọya loun talasan o ba rokun. Wọn ni n jẹ ti Ọya ba burinburin, to rin tititi, to dele Ira, ni wọn ba pọda to tobi, ti wọn fun un ni… ebgo, ikoko egbo nkọ? Ọya ni toun ba ti yo tan, o loun o pada ile oun ni. Wọn ni Ọya o talasan o ba rokun.Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ooṣanla loun talasan ba rokun. Wọn ni n jẹ ti Ooṣanla ba rin tititi, to burinburin, to dele Ifọn, nile baba rẹ, ti wọn fun un lagbebọ adiẹ to royin ti wọn pa a, ati igbin, atiọbẹ oṣiki [egusi]. Oun ni to ba ti yo tan, o loun o pada ile oun ni. Wọn lOoṣanla o talasan ba rokun.Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ẹlẹgba, o loun talasan o ba rokun. Iyẹn Eṣu. Wọn lo o talasan ba rokun. O loun talasan ba rokun. Wọn ni to ba rin tititi, to burinburin, to dele Ketu, nile baba rẹ nkọ? Ti wọn pakukọ adiẹ, ti wọn fun un lepo pupa. Ẹlẹgba ni to ba ti yo tan, o loun o pada ile oun ni.Wọn lẸlẹgba o talasan o ba rokun.Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ogun, o loun talasan o ba rokun. Wọn ni n je tOgun ba burunburin, to rin tititi, to de Ire nile baba rẹ nkọ? Tan fun un lẹmu,tan fun un ni ẹwa ẹyan, tan bẹ aja fun un nkọ? O ni toun ba ti yo tan, oun ni ijala loun maa kẹ tan tan tan, toun ma dari lọle. Wọn ni Ṣango… O lOgun… Wọn ni o talasan ba rokun.Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, wọn ni ta lo talasan ba rokun? Ọrunmila loun talasan ba rokun. Wọn ni to ba burinburin, to rin tititi, to de Okegẹti, nile baba rẹ nkọ? Ọrunmila, tan fun ọ ni abodiẹ meji, abẹdọ rukẹruke, ewurẹ meji, abọmurẹdẹrẹdẹ, ti wọn gunyan, tan fun ọ leku ati ẹja nkọ? Ati ọti? O ni toun ba ti yo tan, o loun a padanile, eni iwọ Ọrunmila papaa, wọn lo o talasan o ba rokun.Ọrunmila ni ta lo talasan o ba rokun? Wọn lori nikan n lọ talasan o ba rokun. Ori ni kan. A kapo ẹju ẹ si. Ọrunmila ni ẹdawọ ọbun kẹ daṣọ romi. Mapo elere, Mọba ọtun, Bọlajoko, Ọkinkin ti merin fọn, o loun… talo da ori ni kan lo talasan ba rokun? Ori ni kan ni… gbe ni, ti n ba n lowo lọwọ, lọwọ ori ni. Ti n ba fẹ aya, ọwọ ori ni. Ti n ba fẹ ọmọ, ori ni. Ti n ba n wa ire gbogbo, ori ni n o ma ro fun o! Ori mi o! Atete niran, atete gbe ni kooṣa. Ko si Ooṣa ti n da ni gbe lẹhin ori. Ori mi pẹlẹ o!Wọn ni ti babalawo ba ku, wọn ni ti babalawo baku, wọn ni akọfa… ẹkofa rẹ dasiko to. Toniṣango ba ku, wọn ni ẹkẹru ẹ danu. Ti Ogun ba ku, wọn ni ẹkẹru ẹ fun ipa. Tooṣanla ba ku, wọn ni ẹ ku ẹru sigbo. Ti eniyan ba ku, ko si eni ti wọn ge oriẹ lẹ. Wọn sin ni mọri ni. Ori ni kan lo talasan ba rokun. Ori mi pẹlẹ atete niran, atete gbe ni kooṣa. Ko si Ooṣa ti da ni gbe lẹhin ori. Ori pẹlẹ o!Ori ni kan lo le ba eniyan ṣe. Ninu gbogbo ohun teniyan ba fẹ ṣe laiye. Ifa ni keleyii o bọ ori daadaa, ko si ma bẹlẹda…ko ma bi ẹlẹda rẹ leereko to le ṣe ohunkohun. Ko ma jọ ara rẹ loju. To ba ti jolowo ko ma…ko ma pe oun ti lowo , mo n lowo o! Mo lọla o, a fi bi mo ba jẹ arẹ orilede. Ifa ni o ko le debẹ ti o ba ti beere lọwọ ori ẹ, bo ti wulẹ ko lowo to. Ifa lori ni kan ni. Ifa sọ bẹẹ loju Ogunda Meji.Ogunda Meji 2:Ẹni ti Ifa [yii] ba tun jade si, ta da Ogunda Meji fun, hun! Tifa ba gbin, tifa gbin, Ifa ni keleyii o rubọ nitori iku o! Ifa ni ko rubọ nitori iku, ti o ni ẹbọ nbẹ, aworan meji lẹbọ ẹ, ookọ meji. Nigba a ba ṣe irubọ yii tan, yio lọ bo aworan yii mọlẹ ẹnu ọna aba wọle ile rẹ ni. A porukọ kan nbẹ, a ge oriẹ si, a sin… a bo mọlẹ. A ba jade lẹkule , a tun gbẹbọ ka nbẹ, a gbe aworan yii bẹ, a tun pookọ kan si, a bo mọlẹ. Ifa ni iku o ni le wọnu ile naa, to ba ti le ṣetutu o. Nibi Ifa n…Ifa gba tifa gbe jẹ bẹ to ti ni o rubọ nitori iku. Ti Ifa ba gbin. O ni:Ka do idobalẹ ka pagbo ọmọ, ka fagbọn isalẹ kan le koro ko ko ko a dia fun aworan dendere, aworan mama de o aboju dendere. Afi bo ba le sunkun, afi to ba le gbẹlẹ, aworan ma de o, aboju dendere.Ifa ni keleyun yio ni aworan meji lẹbọ. Awọran nio ma da, tiku ba ti n bọ, to fẹ wọle, awọran ni yio da pada. Ki eleyun o rubọ nitori iku. Ifa sọ bẹẹ, loju Ogunda Meji.Ogunda Meji 3:Ka ba tun dafa fun eniyan. Ti Ifa nna tun fore. Ifani eleyun, obinrin kan lo fẹ fẹ un. O fẹ gba ni. Obinrin naa ti bimọ sibi kan ri, tabi ẹni kan ti fẹ obinrin yii tẹlẹ. O wa fẹ gba lati ibi tọ wa. Ifa ni ko gba a, o ni a gba gbe, ni o gba, pe ko si wahala. Pe yiọ ṣẹgun nbẹ. Loju Ogunda Meji, Ifa sọ bẹẹ. Nibi ifa gba to fi sọ bẹẹ. O ni:Aguru maguda aguru maguda bi ida o ba sunwọn eji apori ida ko tun dagun a dia fun Ọrunmila, baba n lọ re gba Dudu Ranran eyi ti ṣeọmọ Alaran Oyigi.Baba ni lo fẹ Dudu Ranran yii, o fẹ lọ gba ni, ti ṣe ọmọ alaran oyigi, lọwọ ọkunrin mii[ran]. Wọn wa sọ fun pe, ko ba…ki baba o rubọ o. Obinrin ti n logba yii, agba [tan] ni o ti ṣẹgun nbẹ. O si rubọ, o gbobinrin yii, lo ṣẹgun. Lawọn kan n ba le ri, wọnlo ku ibi ti o gba. Wọn ni aaa, o baba ni irọ lẹ pa, o lagbara yin o le ka oun. Nan ba ṣẹgun nbẹ. Ni n ba n jo ni n ba n yọ. Ni n yan awọn awo, awọn awo rẹ n yin Ifa. O ni bẹẹ babalawo toun [wi] bẹẹ, babalawo toun sọ:Aguru maguda aguru maguda bi ida o ba sunwọn eji apori ida ko to dagun a dia fun Ọrunmila, baba n lọ re gba dudu ranran eyi ti ṣe ọmọ alaran oyigi. Oṣo ni n ba n pe ori mi nibi. Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, bi iṣẹ rẹ ba fọ, wọn sin lẹhin Ṣangoni. Bi babalawo ni n ba n pe ori mi nibi. Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, babiku ba ku tan, wọn sin lẹhin asẹ. O lọkunrin, o lobinrin ni n ba peri mi nibi. Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, Eṣu ni rẹhin ẹni to ri i. Ifa lemi ni mo rẹhin awọn ọta mi.Ifa sọ bẹẹ pe eleyun yio rẹyin gbogbo awọn tan gba n gbogun ti nbẹ. Loju Ogunda Meji o sọ bẹẹ. Ifa ni eleyun ko, ko mura daadaa ko si ma ṣadura daadaa, ko ma beere ohun gbogbo lọwọ ori rẹ ko to ma ṣe gbogbo ohun to ba ṣe loju Ogunda Meji o. O ni aṣeyori wa fun un.Ogunda Meji 4:Ifa ni… o tun sọ bẹẹ, pe eleyii yio ni ọpọlọpọ ire. Agbọn obi kan lẹbọ rẹ nbẹ, ni o ni lẹbọ nbẹ. Kọpọlọpọ ire oun o le to lọwọ, ko le tọ lẹnu [authority]. Ifa ni ọna re n bọ wa fun eleyii, ọna yio ṣi fun un daadaa. Ko lọpọlọpọ obi lẹbọ o, agbọn kan ni. One basket of kola, lo gbọdọ ni lẹbọ nbẹ, pẹlu ọpọlọpọ owo. Ifa ni o gbọdọ ri owo, yio rire gbogbo, ọna rẹ o la. Nibi ifa gba to fi sọ bẹẹ ni o. O ni:Ọpanrun ṣekeṣeke ẹti Yẹmẹtu a difa fun ọlọmọ afẹhinti jagbọn obi. Ki n to rẹni to ṣẹfẹhinti jagbọn obi tan, ire gbogbo to ni lọwọ, ire gbogboa to ni lẹnu.Ifa ni ire gbogbo o teleyun lọwọ, yio to lẹnu. Ko ṣetutu nbẹ. Igbesiaye rẹ yio dun rinrin. Na ba dafa fun, agbọn obi ti o wa nlẹ ti… to fi rubọ, o baku iyẹrosun si. Wọn ni ko lọ ma jẹ, to ba ti lọ, to ba ti n bo ni yio ba mu jẹ to ba… beniyan ba wa dee lalejo, yio fun lobi, bi eniyan… ah, ni gbogbo rẹ… ni awọn eniyan ṣadura fun, ẹṣe o! Aṣiri yin a ma bo, nkan. Bi aṣiri rẹ ṣe n bo nu un, bo ṣe n lowo nu un. Tawọn ọkunrin ṣadura fun un, tobinrin ṣadura fun lọna rẹ ba la. Ifa lọna ni eleyii yio la, yio si ni ọpọlọpọ owo. Ifa sọ bẹẹ lodu Ogunda Meji o. Abọru abọye o. N togunda Meji sọ re o.
Translation
Ogunda Meji 1:I
Ifa says, for anyone for whom Ogunda Meji is cast, Ifa says that in everything that this person wants to do, (s)he should consult his/her destiny [Ori] first. Ifa says his/her destiny is the only one who can grant him/her success. This person should not struggle on his or her own and should not think that when (s)he is rich, andthat (s)he will succeed as a result of that wealth. When (s)he has a job or position, that this position or job will allow him/her to achievewhat (s)he wants. This person should think about his/her Ori and what it has ordained for him/her. (S)He should not say that (s)he is able to do this for him/herself. There is no power greater that Ori! No matter how much money (s)he has,… If (s)he wants to become president, (s)he should worship his/her ori. (S)He should ask his/her destiny if this is in accordance his/her destiny. Before (s)he does it. His/her Oriwill answer him/her. If it is fitting, if it is indeed fitting, then, Ori will say that (s)he should do it but should not think that money will accomplishit! Or that (s)he alone can do it! Ifa says there is no god who supports us like Ori. Yes, Ifa says so.When all of the gods, in the time of the ancestors, they wondered who was the most powerful. Oriṣanla said he was powerful and could do exactly as Olodumare [Almighty God] can do. Ṣango said he was as powerful as Olodumare. He forgot that Olodumare had created every one of them. Even Ọrunmila said that he was as powerful as Olodumare. We are told that there was no one among them who is as powerful as Olodumare. We are told that Ori was the only one amongst the gods who could do as Olodumare did, because Olodumare created humans in His own image and made the head ruler of the everything. That is why Ori [the head] was placed on the top of the body. Oriwas the only one who offered a sacrdifice in thetime of the ancestors. Ifa says in everything thisperson wants to do, if (s)he wants to be president, or governor, or a farmer, or a business person, (s)he should ask his creator [Ori] before taking that path. Perhaps (s)he heard that there is business to be done in Oyinbo’s [white person’s] country, in Washington, that trading gold is lucrative, or in Chicago. (S)he should ask before going there todo business. If (s)he worships his/her Ori carefully and consults Ori, it will not be for nothing. Ifa says so in Ogunda Meji. This is howIfa said it:Ọrunmila ni o dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ṣango loun talasan o ba rokun. Wọn ni ti Ṣango ba burinburin, to ba rin tititi, to de Koso, nile baba rẹ nkọ? Ti wọn fun un lorogbo ati akukọ adiẹ? Ṣango ni toun ba ti yo tan, o loun o pada nile oun ni. Wọn ni Ṣango o talasan o ba rokun.[Ọrunmila says it has ended before it has even begun. Ifa says who has the skill to go on a voyage (overseas) like Alasan? Ṣango said he could make the trip. And what happened when Ṣango had traveled far, when he had walked a great distance and come to Koso, his hometown? When he was given kola nuts and rooster meat to eat? Ṣango said when he had eaten his full, he said he would turn back. Ṣangowas not able to complete the journey.]Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ọya loun talasan o ba rokun. Wọn ni n jẹ ti Ọya ba burinburin, to rin tititi, to dele Ira, ni wọn ba pọda to tobi, ti wọn fun un ni… ebgo, ikoko egbo nkọ? Ọya ni toun ba ti yo tan, o loun o pada ile oun ni. Wọn ni Ọya o talasan o ba rokun.[Ọrunmila says it has ended before it has even begun. Ifa says who has the skill to go on a voyage (overseas) like Alasan? Ọya said she could make the trip. And what happened when Ọya had traveled far, when she had walked a great distance and come to Ira, her hometown? When a fat young bull had been killed for her and she was given egbo [a meal of corn], a whole large pot of egbo? Ọya said when she had eaten her full, she said she would turn back. Ọya was not able to complete the journey.]Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ooṣanla loun talasan ba rokun. Wọn ni n jẹ ti Ooṣanla ba rin tititi, to burinburin, to dele Ifọn, nile baba rẹ, ti wọn fun un lagbebọ adiẹ [hen that is beginning to lay eggs] to royin ti wọn pa a, ati igbin, ati ọbẹ oṣiki [egusi]. Oun ni to ba ti yo tan, o loun o pada ile oun ni. Wọn lOoṣanla o talasan ba rokun.[Ọrunmila says it has ended before it has even begun. Ifa says who has the skill to go on a voyage (overseas) like Alasan? Oriṣanla said he could make the trip. And what happened when Oriṣanla had traveled far, when he had walked a great distance and come to Ifọn, his hometown?When he was given a hen that had just begun tolay eggs that they had just killed for him, and snails, and egusi stew? Oriṣanla said when he had eaten his full, he said he would turn back. Oriṣanla was not able to complete the journey.]Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ẹlẹgba, o loun talasan o ba rokun. Iyẹn Eṣu. Wọn lo o talasan ba rokun. O loun talasan ba rokun. Wọn ni to ba rin tititi, to burinburin, to dele Ketu, nile baba rẹ nkọ? Ti wọn pakukọ adiẹ, ti wọn fun un lepo pupa. Ẹlẹgba ni to ba ti yo tan, o loun o pada ile oun ni.Wọn lẸlẹgba o talasan o ba rokun.[Ọrunmila says it has ended before it has even begun. Ifa says who has the skill to go on a voyage (overseas) like Alasan? Ẹlẹgba said he could make the journey. Ẹlẹgba is Eṣu. They sayhe could not complete the journey. He said he could complete the journey. And what happened when Ẹlẹgba had traveled far, when he had walked a great distance and come to Ketu, his hometown? When they killed a hen for him and gave him red palm oil? Ẹlẹgba said when he had eaten his full, he said he would turn back. Ẹlẹgba was not able to complete the journey.]Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, Ifa ni ta lo talasan ba rokun? Ogun, o loun talasan o ba rokun. Wọn ni n je tOgun ba burunburin, to rin tititi, to de Ire nile baba rẹ nkọ? Tan fun un lẹmu,tan fun un ni ẹwa ẹyan, tan bẹ aja fun un nkọ? O ni toun ba ti yo tan, oun ni ijala loun maa kẹ tan tan tan, toun ma dari lọle. Wọn ni Ṣango… O lOgun… Wọn ni o talasan ba rokun.[Ọrunmila says it has ended before it has even begun. Ifa says who has the skill to go on a voyage (overseas) like Alasan? Ogun said he could make the trip. And what happened when Ogun had traveled far, when he had walked a great distance and come to Ire, his hometown? When he was given palm wine, roasted beans, and they prepared a meal of dog for him? Ogun said when he had eaten his full, he said he would sing his hunter’s songs all the way home.Ogun was not able to complete the journey.]Ọrunmila tun lo dọdẹdẹ nbẹrẹ, wọn ni ta lo talasan ba rokun? Ọrunmila loun talasan ba rokun. Wọn ni to ba burinburin, to rin tititi, to de Okegẹti, nile baba rẹ nkọ? Ọrunmila, tan fun ọ ni abodiẹ meji, abẹdọ rukẹruke, ewurẹ meji, abọmurẹdẹrẹdẹ, ti wọn gunyan, tan fun ọ leku ati ẹja nkọ? Ati ọti? O ni toun ba ti yo tan, o loun a padanile, eni iwọ Ọrunmila papaa, wọn lo o talasan o ba rokun.[Ọrunmila says it has ended before it has even begun. Ifa says who has the skill to go on a voyage (overseas) like Alasan? Ọrunmila said he could make the trip. And what happened when Ọrunmila had traveled far, when he had walked a great distance and come to Okegẹti, his hometown? When he was given two fattened hens, two fattened she-goats, yam waspounded for him, and he was given rats and fishand alchohol? Ọrunmila said when he had eatenhis full, he said he would turn back home. Even the great Ọrunmila could not complete the journey.]Ọrunmila ni ta lo talasan o ba rokun? Wọn lori nikan n lọ talasan o ba rokun. Ori ni kan. A kapo ẹju ẹ si. Ọrunmila ni ẹdawọ ọbun kẹ daṣọ [aro] rọmi. Mapo elere, Mọba ọtun, Bọlajoko, Ọkinkin ti mẹrin fọn, o loun… talo da ori ni kan lo talasan ba rokun? Ori ni kan ni… gbe ni, ti n ba lowo lọwọ, lọwọ ori ni. Ti n ba fẹ aya, ọwọ ori ni. Ti n ba fẹ ọmọ, ori ni. Ti n ba n wa ire gbogbo, ori ni n o ma ro fun o! Ori mi o! Atete nirẹ, atete gbe ni kooṣa. Ko si Ooṣa ti n da ni gbe lẹhin ori. Ori mi pẹlẹ o![Ọrunmila says who has the skill to go on a voyage (overseas) like Alasan? Ori was the only one who could make the trip. Ori is the only one.Ọrunmila says you cover a dirty person with dyed cloth. [Praise names for O\ori], the one who makes the elephant blow its horn, ori is theonly one who can complete the journey. If you have money, it is the work of ori. If you want a wife, it is ori. If you want children, it is ori. If you are searching for any blessing, it is to ori that you muct bring your supplications! O my ori! Ori is always the first to remember me, who will quickly carry me to the Orisa, my helper. There is no god who supports us like ori. My ori, I salute you!]Wọn ni ti babalawo ba ku, wọn ni ti babalawo baku, wọn ni akọfa… ẹkofa rẹ dasiko to. Toniṣango ba ku, wọn ni ẹkẹru ẹ danu. Ti Ogun ba ku, wọn ni ẹkẹru ẹ fun ipa. Tooṣanla ba ku, wọn ni ẹ ku ẹru sigbo. Ti eniyan ba ku, ko si eni ti wọn ge oriẹ lẹ. Wọn sin ni mọri ni. Ori ni kan lo talasan ba rokun. Ori mi pẹlẹ atete niran, atete gbe ni kooṣa. Ko si Ooṣa ti da ni pe lẹhin ori. Ori pẹlẹ o![They say when a babalawo dies, we must bury him with his Ifa. When a devotee of Ṣango dies, we throw away his effects. When a devotee of Ogun dies, hunters take his effects and performthe “ipa” rituals with them. When a devotee of Oriṣanla dies, we throw his effects into the bush. However, when a person dies, nobody willtake away his head. A person is buried with his/her head. Ori is the only one who can make the journey like Alasan. I greet you ori, who is always the first to remember me, who will quickly carry me to the Orisa, my helper. There is no god who supports us like ori. Ori, I salute you!]Ori is the only one who can help this person succeed. In everything that (s)he wants to accomplish in life. Ifa says this person should be sure to worship his/her ori and ask ori beforedoing anything. (S)He should not think too highly of him/herself. If (s)he is rich, (s)he should not think, I’m rich! I’m respected! They can make me president. Ifa says (s)he cannot achieve this if (s)he doesn’t ask his/her ori first (No matter how rich he is). Ifa says it is only Ori.Ifa says so in Ogunda Meji.
Ogunda Meji 2:
If Ogunda Meji is cast for a person, if the message is negative, Ifa says this person needsto make a sacrifice because of death. Ifa says (s)he should make a sacrifice because of death and that (s)he should have two statues and two he-goats in the sacrifice. When the sacrifice is finished, (s)he should bury one statue at the entrance to his/her house. Then (s)he should kill the goat and cut its head, then bury them. Then (s)he should do likewise at the back door of the house, slaughter the goat, and bury the statue. Ifa says that death will not be able to enter the house if (s)he makes the sacrifice. If Ifa says (s)he should sacrifice because of death. If Ifa’s message is negative. Ifa says:Ka to dobalẹ ka pa igba ọmọ, ka fagbọn isalẹ kan le koroko ko ko a dia fun awọran dendere, awọran ma ma de o aboju dendere. Afi bo ba le sunkun, afi to ba le gbẹlẹ, awọran ma de o, aboju dendere.[Let us prostrate, let us make a circle of children, let us put our chin down cast Ifa for the picture that looks so lifeless, who arrived with a lifeless face. Unless it can cry or you can dig, the statue arrives with a lifeless face.]Ifa says this person should have two statues in the sacrifice. When death is coming and wants to enter the house, the statue will repel it. This person should make a sacrifice because of death. This is what Ifa says in Ogunda Meji.
Ogunda Meji 3:
If Ifa reveals a positive message, Ifa says that person wants to marry a certain woman. He wants to take her from someone else. The woman has already had a child, or someone else has already married the woman before. He wants to take her away from her current situation. Ifa says he should do it, that he will have her for good, and that there is no problem at all. He will be victorious. This is what Ifa saysin Ogunda Meji. This is how Ifa said it, Ifa said:Aguru maguda aguru maguda bi ida o ba sunwọn eji apori ida ko tun dagun a dia fun Ọrunmila, baba n lọ re gba Dudu Ranran eyi ti ṣeọmọ Alaran Oyigi.[Aguru maguda aguru maguda when the clay is not good, let us intervene before it gets worse cast Ifa for Ọrunmila when baba was going to take the dark-skinned daughter of Alaran Oyigi (the powerful owner of multicolored clothing) from another man to be his wife.]Our father, Ọrunmila, wanted to marry Dudu Ranran (the dark-skinned woman), who was the child of Alaran Oyigi, although she was the wife of another man. He was told to offer a sacrifice and that he would be successful in his endeavour. He performed the sacrifice, he took the woman, and he was victorious. Some said, he could never take her, but baba told them theywere lying and that their power could never match up to his own. He was victorious. He danced and rejoiced. He praised the Ifa priests, and they in turn praised Ifa. He said, yes the babalawo said so, yes the babalawo told me:Aguru maguda aguru maguda bi ida o ba sunwọn eji apori ida ko to dagun a dia fun Ọrunmila, baba n lọ re gba dudu ranran eyi ti ṣe ọmọ alaran oyigi. Oṣo ni n ba n pe ori mi nibi. Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, bi iṣẹ rẹ ba fọ, wọn sin lẹhin Ṣangoni. Bi babalawo ni n ba n pe ori mi nibi. Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, babiku ba ku tan, wọn sin lẹhin aṣẹ. O lọkunrin, o lobinrin ni n ba peri mi nibi. Ẹ jọọ mi, ẹ ju ẹ, Eṣu ni rẹhin ẹni to ri i. Ifa lemi ni mo rẹhin awọn ọta mi.[Aguru maguda aguru maguda when the clay is not good, let us intervene before it gets worse cast Ifa for Ọrunmila when baba was going to take the dark-skinned daughter of Alaran Oyigi (the powerful owner of multicolored clothing) from another man to be his wife. If a sorcerer wants to curse me, let me deal with him, leave him for me. When his efforts fail, we will offer him to Ṣango. If a babalawo wants to curse me let me deal with him, leave him to me. When an abiku child has finally died, it will simply be discarded without a funeral. If any man or any woman tries to curse me, let me deal with him/her, leave it to me. Eṣu will always triumph over his enemies. Ifa let me triumph over my enemies.]Ifa says that this person will triumph over all of the people who are fighting him/her. Ogunda Meji says so. Ifa says in Ogunda Meji that that person should be very careful and pray ferventlyand ask for all that he wants from his/her ori before pursuing it. Ifa says that success is there for him/her.Ogunda Meji 4:Ifa also says that this person will have many blessings. A basket full of kola nuts is the prescribed sacrifice so that (s)he will gain mmany blessings and authority. Ifa says that this persons way will open up and be made easy. (S)He should include lots of kola nut in the sacrifice, one whole basketful. One basket of kola is what must be in the sacrifice with lotsof money. Ifa says (s)he will surely come into money, all kinds of blessings, and his/her way will open up. This is how Ifa said it:Ọpanrun ṣekeṣeke ẹti Yẹmẹtu a difa fun ọlọmọ afẹhinti jagbọn obi. Ki n to rẹni to ṣẹfẹhinti jagbọn obi tan, ire gbogbo to ni lọwọ, ire gbogboa to ni lẹnu.[The bramble tree ṣekeṣeke near Yẹmẹtu (a neighborhood in neighborhood) cast Ifa for someone who reclines and eats an entire baskt of kola nuts. Before I see a person who reclines and eats a whole basket of kola nuts, he receives blessings, he enjoys blessings.]Ifa says that person will experience all kinds of blessings and should make an offering. His/herlife will be incredibly enjoyable. If Ogunda Meji is cast for someone, iyẹrosun [Ifa camwood powder] should also be sprinkled over the basket of kola used for the sacrifice. The person should eat the kola nuts as (s)he s going and coming, and when a guest or stranger passes by, (s)he should offer him/her some kola nuts. They will pray for him/her saying, “Ah, thank you o! May you always posses the secret of your success! That is how (s)he will come to gain money. Both men and women pray for him/her and prosper. Ifa says this person’s road will open up, and (s)he will have lots of money.


No comments:

Post a Comment

Note: Only a member of this blog may post a comment.

Featured post

Work-Life Balance - How to Protect Your Boundaries When Your Company Is Struggling - Sun and Planets Spirituality AYINRIN

 Work-Life Balance -  How to Protect Your Boundaries When Your Company Is Struggling - Sun and Planets Spirituality AYINRIN HBR Staff/Unspla...